NLC: Àwọn òsìsẹ́ Naijiria ló ń gba owó osù tó kéré jù!

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ osisẹ lorilẹede Naijiria,NLC ti ni idi ti awọn fi kọ ẹgbẹrun lọna mẹtadinlọgbọn(27,000) Naira ti ijọba fi ọwọ si gẹgẹ bi gbendeke owo osu awọn osisẹ lorilẹede Naijiria ni wi pe ijọba ko mu adehun wọn sẹ.
Alaga ẹgbẹ osisẹ ni ipinlẹ Osun, Komreedi Babatunde Adekomi to sọ eyi lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori idi ti wọn fi kọ gbedeke owo osu osisẹ, ni awọn osisẹ Naijiria lo n gba owo osu to kere ju lọ ni Afirika.
Adekomi ni ẹgbẹrun lọna mẹtalelọgbọn (33,000) Naira ni igbimọ ti ijọba gbe kalẹ bu ọwọ lu lasiko ipade wọn , ki wọn to lo o gbe e fun ijọba apapọ lati fi ontẹ lu u.
O ni gbogbo nkan ni awọn gbeyẹwo ko to di wi pe awọn fẹnuko lori gbedeke owo osu ti awọn fẹ ma a gba.
Alaga ẹgbẹ osisẹ naa ni awọn gbe ọrọ aje Naijiria wo, owo ti awọn eniyan fi n wọ ọkọ, ile ti awọn eniyan n gbe, ati ọpọlọpọ nkan miran ni awọn gbe yẹwo.
Komreedi Babatunde Adekomi fikun wi pe awọn osisẹ lorilẹede Naijiria lo gba owo osu to kerejulọ lagbaye, ti iya ati isẹ si n koju awọn eniyan.
O wa fikun wi pe ijọba o sọ idi ti wọn fi din owo naa ku, ati wi pe ẹgbẹ osisẹ yoo ma se ipade ni Ọjọ Ẹti, ọsẹ yii ni ilu Abuja lati mọ igbesẹ to ku ti wọn yoo gbe.










