Minimum wage: 30,000 Naira ni ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ n bèèrè fún

Ọpọ ero nibi iwọde kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọ̀rọ̀ ẹ̀kúnwó oṣù tuntun ló ń fa èdèàìyedè láàárín ìjọba àpapọ̀ àti àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà

Ẹgbẹ osisẹ lorilẹ-ede Naijiria ti kọ lati gba ẹgbẹrun lọna mẹtadinlọgbọn gẹgẹ bi gbẹndeke owo osu awọn osisẹ lorilẹ-ede Naijiria.

Akowe gbogboogbo fun ẹgbẹ osisẹ naa, Ọmọwe Peter Ozo-Eson lo fi ọrọ yii lede fun awọn oniroyin ni ọjọ Isẹgun ni Abuja to jẹ olu-ilu orilẹ-ede Naijiria.

Ozo-Eson ni ijọba apapọ ko lasẹ lati yii adehun ti igbimọ onigun mẹta gbe le Aarẹ Buhari lọwọ pe ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira ni awọn fẹ ma a gba gẹgẹ bi gbendeke owo osu.

Ẹgbẹ NLC wa kilọ fun ijọba apapọ pe gbogbo awọn osisẹ lorilẹ-ede Naijiria ni yoo da isẹ silẹ, ti ijọba ko ba ṣe ohun totọ lasiko.

Igbìmọ̀ májẹ̀-kó-bàjẹ́ Nàìjíríà tẹ́wọ́ gba #27, 000 owó oṣù òṣìṣẹ́

O le ni ọdun mẹwaa ti ẹkunwo owó ọya awọn oṣiṣe Naijiria ti jẹ ẹgbẹrun mejidinlogun.

Ipade awọn igbimọ ijọba apapọ pawọpọ fẹnuko pé ẹgbẹrun mẹtadinlọgbọn ni awọn yoo maa san fawọn oṣiṣe Naijiria.

buhari

Oríṣun àwòrán, @presidency

Àkọlé àwòrán, Buhari gba lati san naira mẹtadinlọgbọn ní owó ọ̀yà òṣìṣẹ́ Naijiria.

Iyẹn lẹyin ọpọlọpọ iwọde, iyanṣẹlodi fun ikilọ ati ifẹhonuhan awọn oṣiṣẹ.

Àkọlé fídíò, Gbade Ojo

Wọn ni kete ti igbimọ yii ti fẹnuko lori odiwọn iye naa ni wọn yoo gbe àbá naa ranṣẹ sawọn aṣojuṣofin lọla ki o le jẹ itẹwọgba.

Iroyin n sọ pé àwọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ṣi n sọ pe ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira ni awọn fẹ ko jẹ owo oṣu oṣiṣẹ to ba kere julọ.

Àkọlé fídíò, Obasanjo: Atiku kìí se Áńgẹ́lì, àmọ́ yóò se dáadáa ní ìlọ́po méjì ju Buhari lọ

Bayii, ti iroyin yii, jade, A ko tii mọ igbesẹ ti ẹgbẹ oṣiṣẹ fẹ gbe, boya wọn maa gba àbá ijọb apapọ wọle tabi bẹẹ kọ.

Bi ọrọ naa ba ṣe n lọ ni BBC Yoruba a maa fi too yin leti ni ikannni yii.

Àkọlé fídíò, Ezekwesili: Àfojúsùn mi ni láti mú ààbò ẹ̀mí ọmọ Nàíjíríà ní ọ̀kúnkúndùn
Àkọlé fídíò, Kinni wọn n pè ni oṣupa déjé ní kíkún?