Ìgbímọ̀ májẹ̀kóbàjẹ́: Buhari, Obasanjo, Jonathan se ìpàdé májẹ̀kóbàjẹ́

Oríṣun àwòrán, @Presidency
Tẹrin-tọyaya ni aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari pẹlu Olusegun Ọbasanjofi ki ara wọn sibi ipade awọn ọmọ igbimọ majẹkobajẹ orilẹede Naijiria.
Ipade naa waye lẹyin ti awọn mejeeji ti sọ oko ọrọ tan si ara lori lẹta ti Ọbasanjọ kọ lati tabuku isejọba Muhammadu Buhari.
Lẹyin ti wọn yọ ki ara wọn tan niBuhari, Ọbasanjọ ati Goodluck Jonathan wa se ipade idakọnkọ, ki wọn to lọ si yara ipade igbimọ majẹobajẹ ilu.
Ipade naa to waye ni ile aarẹ ni Abuja, bẹrẹ lagogo mọkanla ni ile aarẹ ni Abuja.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Awọn to wa ni ibi ipade naa ni Adari Orilẹede Naijiria tẹlẹri, awọn Adajọ Agba Naijiria, Ile Igbimọ Asofin, awọn gomina laaarin awọn miran.

Oríṣun àwòrán, @Presidency
Lara wọn ni Oloye Olusegun Obasanjo, Abdulsalami Abubakar ati Goodluck Jonathan, Igbakeji Aarẹ, Yemi Osinbajo, Aarẹ iIe Igbimọ Asofin, Bukola Saraki, Adajọ Agba Tẹlẹri, Mohammed Uwais, ti Aarẹ Buhari si fọwọbọwọ pẹlu wọn.
Awọn gomina ipinlẹ Osun, Kebbi, Zamfara Plateau, Ebonyi, Adamawa, Edo, Lagos, Niger, Borno, Ogun, Ekiti, ati Kogi ko gbẹyin ni ibi ipade igbimọ majẹkobajẹ yii.

Oríṣun àwòrán, @Presidency
Amọ adari tẹlẹri, Yakubu Gowon, Ibrahim Babangida ati Adajo Agba tẹlẹri, CJN Mariam Muktar kọ iwe ransẹ wi pe, awọn ko ni le kopa ninu ipade naa.













