Melaye: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tún ka ẹ̀ṣùn mẹ́sàn-án mọ́ Dino lọ́rùn

Dino Melaye

Bi o tilẹ jẹ pe ileẹjọ giga ilu Abuja ti pasẹ pe ki wọn gba oniduro sẹnatọ to n soju ẹkun idibo iwọ oorun Kogi, Dino Melaye kuro ni ahamọ awọn ọlọpa, sib aasofin agba naa ko lee lọ sile.

Ọjọ Aje ni Melaye pari gbogbo gbedeke ti adajọ so mọ gbigba oniduro rẹ, to si n reti ati lọ sile, amọ ireti naa ja si pabo, pẹlu bawọn ọlọpaa se tun we awọn ẹsun miran kọ lọrun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Obasanjo: Atiku kìí se Áńgẹ́lì, àmọ́ yóò se dáadáa ní ìlọ́po méjì ju Buhari lọ

Ọrọ Dino Melaye yii, lo tun di egbinrin ọtẹ, ba ti n pakan, ni omiran n ru, pẹlu ẹsun onikoko mẹsan tileesẹ ọlọpa tun to mọ lọrun, ati ẹ́nikan ti wọn pe ni Silas Omenka.

Ninu ẹsun tuntun yii ni wn ti tọkasi pe Melaye tapa si ofin pe kawọn ọlọpa gbee, to si tun fẹsun kan ọga agba ọlọpa tẹlẹ, Ibrahim Idris, pe o n gbero lati gun oun ni abẹrẹ iku, eyi ti wọn lo tapa si ofin ilẹ wa.

Ọjọ Isẹgun si ni ireti wa pe Dino yoo tun pada yọju sile ẹjọ lori awọn ẹsun tuntun yii.