Etí òkun: Ọ̀pọ̀ ẹlẹ́ṣin ń pa tó ₦10,000 lójúmọ́

Awọn to n gbe niluu Eko, maa n lọ si eti okun lati gba afẹfẹ to yatọ si ti aarin ilu.
Wọn maa n wọ ọkọ oju omi, gbafẹ, gba bọọlu tabi ṣe ayẹyẹ. Ṣugbọn, awọn to laya le san owo lati gun ẹṣin - pẹlu iranlọwọ awọn ẹlẹṣin to wa leti okun.

Quadri Raji, ẹni ọdun mọkandinlogun n ṣiṣẹ atun foonu ṣe larin ọṣẹ, ṣugbọn o maa n fi ẹṣin siṣẹ leti òkun Atlantic l'opin ọsẹ.
O pa ẹ̀kọ́ rẹ ti nileewe girama nigba ti wọn ge ẹsẹ iya rẹ lẹyin ijamba kan.

Nibayi, oun n tọju ara rẹ, o si ni ireti pe ẹṣin yii yoo pa owo ti yoo to, lati ṣe idanwo aṣejade ileewe girama.
''O wumi lati tẹsiwaju ninu ẹ̀kọ́ mi, àmọ́ bayii iṣẹ kan yii ni mo n ṣe lati pawo wọle.
Leti okun, Quadri maa n pa to ẹgbẹrun mẹwa Naira lójúmọ́.

Ẹṣin rẹ, Jack, maa n jo lasiko awọn ọdun ibilẹ, ṣugbọn Quadri ti n kọ ọ lati ṣiṣẹ leti òkun.
O si maa n ṣe daada.

Tunde Sanni (to wa lapa òsì), jẹ ẹni ọdun mejidinlọgbọn. O si ti n gun ẹṣin leti òkun ju ọdun mẹtala lọ, oun si ni alaga ẹgbẹ awọn to n gun ẹṣin ni eti okun Atican.
Ọdun 2008 ni awọn obi rẹ ku, o si tun n ṣiṣẹ ajorin-mọrin.
"Ẹṣin gigun si ti gba ole jija lọwọ mi."

Àpá kan wa niwaju ori Tunde, eyi to waye lasiko to jabọ lori ẹṣin nigba ti ọkọ ayọkẹlẹ kan gba a lasiko to n gun ẹṣin lọdun 2010.

'Stone' jẹ ọkan lara ẹṣin mẹta to ni, Oun naa lo ni 'Prince ati 'Pale.'

Ẹni ọgbọn ọdun ni Lanre, o si ti n ṣiṣẹ ẹṣin gigun leti okun fun ọdun mẹta.
Bakan naa lo maa n ta ewurẹ ati tolotolo ni ọja ẹran ọsin. Opin ọsẹ lo maa n mu ẹṣin rẹ, 'Spaghetti', lọ si eti okun lati pawo si i.
"Mo niyawo ati ọmọ meji ti mo n bọ ọ, nitori naa ni mo ṣe n gba ọna mi i lati pawo wọle.''

Ẹṣin Adebọwale Dada, Jerry, maa n ṣiṣẹ tẹlẹ fun ere sisa. O ra a ni igba ẹgbẹrun ati mẹtalelaadọta Naira, niluu Kano lọdun to kọja.
"Iṣẹ kan ti mo n ṣe niyii, mo si niyawo ti mo n tọju. Bakan naa ni mo n fi owo pamọ fun owo ileewe awọn ọmọ mi."

Bi ẹẹdẹgbẹta Naira si ẹgbẹrun kan Naira ni awọn eniyan maa n san lati gun ẹṣin, awọn ẹlẹṣin a si maa rin pẹlu wọn.

Igba akọkọ niyii ti Favour Eric yoo gun ẹṣin. ''Ẹru ba mi o, ṣugbọn mo gbadun ara mi.''

Awọn ẹlẹṣin yii jẹ diẹ lara awọn ẹgbẹ wọn o n wa awọn ọna ti ko wọpọ lati wa owo, nigba ti iṣẹ oṣu ko si nigboro.

Awọn aworan yii wa lati ọwọ oṣiṣẹ BBC, Grace Ekpu.












