Falomo: Ó yẹ kí Obasanjo ti jẹ asaájú Yorùbá, àmọ́ kò leè jẹ́
Dokita Ore Falomo ati Sẹnatọ Fẹmi Okurounmu, tii wọn jẹ agbaagba nilẹ Yoruba, ti fesi si awọn koko ọrọ ti Oloye Olusẹgun Ọbasanjọ sọ nipa isejọba Buhari.
Lero ti Ọrẹ Falọmọ, agba ti n da Ọbasanjo laamu, ko si yẹ ka tẹti si awọn ọrọ rẹ mọ.
Falọmọ ni Ọbasanjọ ko mọ ohun to n se mọ, idi si ree ti a ko se fi jẹ asaaju ilẹ Yoruba lati ọjọ pipẹ wa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹgbẹ́ alátakò fẹ́ lo Boko Haram láti da ìbò 2019 rú - Lai Muhammed
- Irú kan náà ni Atiku àti Buhari, kò s'íyàtọ̀ nínú wọn - Tunde Bakare
- Ẹ̀rò àwọn ènìyàn se ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí lẹ́tà Ọbasanjo sí Buhari
- Ọbasanjọ: Ó yẹ kí Amina Zakari kọ̀wé fipò sílẹ̀
- Kíni ìwọ mọ̀ nípa Funmilayọ Ransome-Kuti?
- Ẹfunsetan Aniwura, obìnrin tó ju ọkùnrin lọ
- Hubert Ogunde rèé, baba àwọn òsèré tíátà
- Kí lo fẹ́ mọ̀ nípa ‘Ajala Travels’?
- Wòlíì Kasali ní Dolapo Awosika kò lé ìyàwó òun jáde
- 'Alífábẹ́ẹ́tì Ohùn Oduduwa di ìtẹ́wọ́gbà ni Ajaṣẹ'
O wa rọ Obasanjọ lati tọrọ idarijin lọdọ Ọlọrun fun bo se da iran Yoruba ati Oloogbe MKO Abiola, pẹlu afikun pe, ko lẹtọ fun Ọbasanjọ lati maa sọ pe Atiku ṣẹ oun.
Nigba to n sọ ero rẹ lori ọrọ ti Ọbasanjọ sọ nipa isejọba Muhammadu Buhari, Sẹnatọ Fẹmi Okurounmu sọ pe, ko si irọ kankan ninu awọn ọrọ ti Ọbasanjọ sọ sita, ija ilu si lo n gbe.
Okunrounmu ni ko bojumu to ki Buhari maa yan ibatan rẹ nikan sipo lai nigbẹkẹle ninu ẹya miran,
Bakan naa lo faramọ ọrọ Ọbasanjọ pe isọwọsisẹ ajọ eleto idibo Inec mu ifura lọwọ.