Lagos Fire Service: Ẹ máse tan àbẹ́là lórí ike tàbí pákó

Ọkọ Panapana

Oríṣun àwòrán, @LAG_FireService

Ọga agba fun ile-isẹ panapana ni ipinlẹ Eko, Rasaki Musibau ti darukọ awọn nkan kekeeke ti a le se, lati dẹkun ijamba ina ninu ile.

Musibau sọ eyi lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori awọn nkan to n fa ijamba ina ninu ile.

O sọrọ nipa pipa ina ọba nigba kiigba ti eniyan ba n jade kuro ninu ile, ati rira agolo ilewọ iyẹfun panapana si inu ile (fire extinguisher).

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Atiku ní òun kò dènà kí ọ̀dọ́ kankan dupò ààrẹ ní Nàìjíríà

Ọga agba ile isẹ panapana naa wa tọka lẹsẹẹsẹ, awọn ohun to n se okunfa ijamba ina ninu ile ati awọn ọna abayọ si ijamba ina ninu ile naa:

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Ọ̀gá àgbà ilé isẹ́ panápaná ní Eko ti pàrọwà sí àwọn ènìyàn láti má se mu sìgá nínú ilé.

Awọn nkan Mẹjọ to n fa ijamba ina ninu ile

  • Titan abẹla lori ike tabi pako le fa ijamba ina ninu ile
  • Ti agbara ina ọba ba pọ ju, ti a ko si pa ina ọba to wọ inu ile
  • Titan ina ọba silẹ ti a ba n jade kuro ninu ile
  • Gbigbe epo bẹntiroolu sinu ile
  • Dida epo bẹntiroolu sinu ẹrọ amunawa lasiko ti o ba si n sisẹ lọwọ
  • Gbigbe agba afẹfẹ gaasi si inu ile tabi ni abẹ tabili ninu yara ti wọn ti n se ounjẹ
  • Sisun igbo ati oko ni ayika ile le fa ijamba
  • Mimu siga ninu ile tabi lasiko ti oorun ba n kun eniyan.

Kini ọna abayọ si ijamba ina ninu ile?

  • Ọga agba ile isẹ panapana ni ipinlẹ Eko ti ni awọn ara ilu gbọdọ ni agolo ilewọ iyẹfun panapana bii meji si inu ile lati tete dawọ ijamba ina duro
  • Ẹ ma a pa gbogbo oju opo ti ina ijọba n gba wọ inu ile, ti a ba n jade kuro ninu ile
  • Gbigbe ẹrọ amunawa ati epo bẹntiroolu kuro ni inu ile
  • Ẹ ma se mu siga ni inu ile
  • Ẹ sun igbo ati koriko ni gbangba pẹlu omi ni tosi lati tete pa ina to ba pọju lasiko ti a ba n jo oko
  • Ẹ lo awọn ẹrọ igbalode to n mu ina wa bii ‘rechargeable lamps’ dipo titan abẹla ninu ile.

Ti ijamba ina ba sẹlẹ, e tete pe ile isẹ panapana lori nọmba wọn: 767 ati 112 ni ipinlẹ Eko.