Dipo Jimoh: Àburo Jimoh Ibrahim ti ní àìbìkítà ẹbí ló pa ìyá òun

Ile kan to n jona

Oríṣun àwòrán, @LAG_FireService

Ọjọ buruku, esu gbomimu, tii se ọjọ manigbagbe ni ọjọ Satide, ọjọ Kọkandinlogun osu Kinni ọdun 2019 jẹ, ninu ile gbajugbaja olokooowo kan, Jimoh Ibrahim nigba ti ijamba ina sadede sẹlẹ ninu ile rẹ, to si mu ẹmi iya to bi saye lọ.

Ọmọ iya to doloogbe naa, Dipo Jimoh to si jẹ aburo Jimoh Ibrahim, ti fi atẹjade sita to sọ wi pe kii se ina abẹla lo pa iya oun ni inu ile Jimọh Ibrahim to wa ni adugbo Victoria Garden City, ni Lekki ni ina ọhun ti sẹyọ ni deede aago kan oru alẹ ọjọ Satide.

Jimoh ni aibikita ẹbi lo se okunfa iku to pa iya oun, ati wi pe kii se ina abẹla lo pa iya oun bii iroyin se gbe e jade.

O fikun wi pe lai pẹ ni oun yoo fi lede lẹkun rẹrẹ bi isẹlẹ naa se waye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Ezekwesili: Àfojúsùn mi ni láti mú ààbò ẹ̀mí ọmọ Nàíjíríà ní ọ̀kúnkúndùn

Iroyin to tẹ wa lọwọ tẹlẹ ni pe iya gbajumọ olokoowo naa, ti orukọ rẹ n jẹ Theresa Jimoh, lo tan abẹla lati fi se adura nitori pe ẹlẹsin ijọ Aguda, Katoliki nii se.

Iroyin naa ni mama Ibrahim Jimoh yii lo sun lọ fọn-fọn lasiko to n gba adura lọwọ, eyi to jo ile ọhun kanlẹ.

Iya agba naa si dagbere faye kawọn osisẹ panapana to de sibi isẹlẹ ọhun lati doola isẹlẹ naa, ti wọn si ti gbe oku rẹ si ile igbokusi.

Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ, Ọgbẹni Ahmadu Sakiru, to jẹ osisẹ alarina fun ileesẹ panapana ipinlẹ Eko ni lootọ ni isẹlẹ naa waye, gbogbo aayan awọn lati doola ẹmi mama agba ọhun lo ja si pabo.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, ''Iná àbẹ́là ló ṣokùnfà bí màmá Jimoh Ibrahim jóná mọ́lé