Ìgbẹ́jọ́ Onnoghen: Ìgbàkejì rèé tí iléẹjọ́ òṣìṣẹ́ yóò dáwọ́ ìgbẹ́jọ́ Onnoghen dúró

Walter Onnoghen

Oríṣun àwòrán, @phrekee

Ileẹjọ to n gbọ aawọ laarin awọn osisẹ ati agbanisisẹ nilẹ Naijiria, NIC, tun ti pasẹ lẹẹkan si pe ki igbimọ olugbẹjọ lori aikede dukia ẹni, CCT, dawọ duro na lori igbẹjọ adajọ agba ilẹwa, Walter Onneghen to fẹ gunle.

Onnoghen lo n koju ẹsun onikoko mẹfa to nii se pẹlu ẹsun pe o kuna lati kede awọn dukia rẹ kan eyiti ileẹjọ to n gbọ ẹsun aikede dukia fi kan-an.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Atiku ní òun kò dènà kí ọ̀dọ́ kankan dupò ààrẹ ní Nàìjíríà

Bẹẹ ba gbagbe, ileẹjọ to n gbọ aawọ laarin awọn osisẹ ati agbanisisẹ naa ti kọkọ kede lọjọ kẹẹdogun osu Kinni ọdun 2019 pe igbimọ olugbẹjọ aikede dukia, CCT, dawọ duro naa lori gbigbọ ẹsun naa, ti wọn si sun igbẹjọ ọhun siwaju di ọjọ kejilelogun osu Kinni ọdun 2019 naa.

Bi ileẹjọ awọn osisẹ naa si tun se n bẹrẹ isẹ loni lo tun pasẹ lẹẹkeji pe igbimọ olugbẹjọ CCT, ko tun gbọdọ joko gbọ ẹjọ naa.