Presidential Debate: Ọ̀rọ̀ bọ́ lórí bí Buhari àti Atiku ṣe kọ̀ láti ṣe ìjírọ̀rọ̀

Oríṣun àwòrán, Connect Nigeria
Ero ọkan awọn ọmọ Naijiria ti lu ori opo ikansira ẹni lori ayelujara pa lori bi Aarẹ Muhammadu Buhari ko ṣe yọju sibi ijiroro laarin awọn oludije fun ipo aarẹ.
Bakan naa ni wọn ko dakẹ lori bi Atiku Abubakar, tọ jẹ oludije fẹgbẹ oṣelu PDP ṣe kọ lati kopa ninu eto ijiroro naa, lẹyin to yọju sibudo ijiroro ọhun.
Bi o tilẹ jẹpe aarẹ Buhari ni eto ti oun ni lo fa sababi aiyọju oun, ti Atiku naa si sọ pe, aiwa Buhari lo jẹ k'oun naa kọ lati kopa ninu eto ọhun, ni ọpọ eeyan bu ẹnu atẹ lu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọrọ ti oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Young Progressive Party, YPP, Kingsley Moghalu sọ lori bi Buhari ati Atiku ko ṣe yọju ni JJ Omojuwa fi lede loju opo Twitter.
Omojuwa woye pe, awọn mejeeji kọ lati yọju nitori wọn ko le dahun awọn ibeere ti wọn yoo bi wọn nibi ijiroro naani.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Bẹẹ lo fi kun ọrọ rẹ pe, o yẹ ki awọn ti wọn ṣagbatẹru eto pe Ọmọyẹle Ṣoworẹ, to jẹ oludije fun ipo aarẹ fun ẹgbẹ oṣelu African Action Congress(AAC) pẹlu.
O ni lawọn orilẹede miran, oludije fun oṣelu le kuna, to ba kọ lati yọju sibi ijiroro iru eyi ti Buahri ati Atiku ko lọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Sẹnẹtọ to n ṣoju aarin gbungbun Ipinlẹ Kaduna, Shehu Sanni naa sọrọ loju opo Twitter tiẹ pe, kii ṣe dandan fun aarẹ Buhari lati kopa ninu ijiroro to waye lalẹ ọjọ Abamẹta naa.
Ninu ọrọ to kọ lede Oyinbo ati Pidgin, o ni wọn kan fẹ tabuku Buhari, ni wọn ṣe sọ pe ko wa kopa ninu ijiroro naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3

End of X post, 4

End of X post, 5
Reno Omokiri, to jẹ eekan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP sọrọ loju opo Twitter rẹ pe, Atiku rinrin ajo fun wakati mẹjila gbako pada wale lati orilẹede Amẹrika, lati wa kopa ninu ijiroro naa.
Reno ni Atiku salaye pe, o jẹ iyalẹnu fun oun pe, aarẹ Buhari ko si nibẹ, eyi lo jẹ ki oun naa kọ lati kopa ninu eto ọhun.
O woye pe, ni ti Atiku, ko si ohun ti Atiku fẹ ṣe nibẹ ti Buhari ko ba si nibi eto naa, bo tilẹ jẹ pe o tọrọ aforiji pe, Atiku ko le kopa ninu ijiroro naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 6