ASUU: Ìpádé míràn pẹ̀lú ìjọba yóò wáyé lọ́jọ́ Ajé

Awọn akẹkọ fasiti to n kẹkọjade

Oríṣun àwòrán, @Official_ASUU

Ẹgbẹ awọn olukọ fasiti ASUU, ati ijọba apapọ yoo tẹsiwaju lọjs aje ninu ijiroro ti wọn n se lati fopin si iyansẹlodi olosu meji tawọn olukọ naa gunle.

Aarẹ apapọ fun ẹgbẹ ASUU, Ọjọgbọn Biọdun Ogunyẹmi lo fidi eyi mulẹ lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ nilu Abuja.

Amọ ko sai yan pe ipade naa ko tums si pe opin yoo ba iyansẹlodi awọn olukọ fasiti naa ni kiakia.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Ezekwesili: Àfojúsùn mi ni láti mú ààbò ẹ̀mí ọmọ Nàíjíríà ní ọ̀kúnkúndùn

Ọjọgbọn Ogunyẹmi ni lọwọlọwọ bayii, ko tii si idagbasoke kankan da bi alara nidi idahun ijọba sawọn ibeere ẹgbẹ ASUU, pẹlu afikun pe lọdun to kọja, ijọba jẹjẹ lati gbe owo kalẹ fawọn ileẹkọ fasiti, amọ to kọ lati se bẹẹ, titi ti iyansẹlodi awọn fi bẹrẹ.

Minisita fun ọrọ osisẹ ati awọn ọmọ ẹgbẹ ASUU n se ipade

Oríṣun àwòrán, @Official_ASUU

"Awọn ọmọ ẹgbẹ wa ni awọn ko fẹ ileri ori ahọn lasan mọ, igbesẹ to loorin lawọn n fẹ nidi gbigbe owo kalẹ fawọn ileẹkọ fasiti. Ijọba si gbọdọ fi da awọn ọmọ ẹgbẹ ASUU loju pe, oun ko tii fi ọwọ rọ adehun wọn danu nipa gbigbe ida owo kan silẹ ninu owo ti wọn n beere fun"

Ọjọgbọn Ogunyẹmi ni lọna ati dena igbesẹ ki ASUU ati ijọba tun sẹsẹ maa jiroro lori sisan ajẹsilẹ owo ajẹmọnu awọn ọmọ ẹgbẹ naa, igun mejeeji ti fẹnu ọrọ jona pe owo ajẹsilẹ naa yoo wọnu eto isun ọdun 2019.