Da Rocha: Ìlú Iléṣà ni bàbá miliọníà àkọ́kọ́ ti wá, àmọ́ ó ṣe ẹrú ní Brazil

Candido Da Rocha

Oríṣun àwòrán, NigerianMuseum

Ni ọpọ igba, lawọn eeyan maa n ṣe apejuwe eeyan kan to ba ri jajẹ ni awujọ pe ẹni naa lowo bii Da Rocha tabi pe o lowo ju Da Rocha lọ.

Fun ọpọ ọmọ ilẹ Yoruba to wa loke eepẹ loni, eti lasan ni wọn fi n gbọ orukọ Da Rocha, wọn ko mọ iru eeyan to jẹ, ti awọn miran tiẹ ro pe arosọ lasan ni, ati pe Da Rocha kii ṣe ọmọ ilẹ Yoruba rara.

Ṣugbọn akọsilẹ lati loju opo itakun agbaye taa ti ko iroyin yii jọ fi ye wa pe, lootọ ni Da Rocha gbe nilu Eko, o lowo lọwọ pupọ nigba aye rẹ, oun si laa lee pe ni Miliọnia akọkọ nil Yoruba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

A gbọ pe Da Rocha ba owo nile ni, tori pe baba rẹ ni owo lọwọ, amọ ti Candido funra rẹ ṣiṣẹ mo owo to ba nile.

Iroyin fi ye wa pe Da Rocha kọle, o kọ aasẹ silu Eko, to si ṣiṣẹ takuntakun lati ri daju pe ilu Eko ni idagbasoke ati awọn ohun eelo amayedẹrun to yẹ nigba to fi wa loke eepẹ.

Àkọlé fídíò, Oluwo‘s Wedding: Àwọn èèyàn ìlú Iwo ní àwọn ń fojú sọ́nà láti tẹ́wọ́gba aya tuntun

Ta ni Miliọnia akọkọ nilẹ Yoruba naa, Da Rocha?

Apetan orukọ rẹ ni Candido Da Rocha, ti orukọ baba rẹ si n jẹ Joao Esan Da Rocha

Baba rẹ yii jẹ ọmọ ilu Ileṣa, ti wọn ko lẹru lọ si orilẹede Brazil lọdun 1840 nigba to wa lọmọ ọdun mẹwa

Ẹsan gba ominira, to si se igbeyawo ni Brazil, o si bi Candido Da Rocha nibẹ lọdun 1860

Candido Da Rocha lọ sile ẹkọ alakọbẹrẹ ni Brazil ko to pada sile lẹyin ti baba rẹ, Ẹsan, tọpasẹ orisun rẹ́ wa silẹ Yoruba, ile ẹkọ girama CMS nilu Eko si ni Da Rocha lọ, nibi to ti jẹ olori awọn akẹkọ, Head Boy

Iroyin ni Da Rocha di olowo lati ipasẹ oyinbo kan to maa n ta goolu, to fẹ pada sile nilẹ Gẹẹsi, to si fẹ ta awọn goolu to ti wa kusa wọn lọdun 1894, eyi to mu ko tọ Da Rocha lọ.

Ile Da Rocha

Oríṣun àwòrán, Nigeria Museum

Da Rocha ni alawọ dudu akọkọ ti yoo da banki silẹ:

Ẹgbẹrun mẹfa owo Pọun ni oyinbo naa fẹ ta goolu rẹ, eyi kọja agbara rẹ, to si lọ gba owoya ni banki lati ra awọn goolu naa

Goolu yii ni Da Rocha ta, to si ri ere gọbọi lori rẹ, eyi to sọọ di olowo jaburata ati Miliọnia akọkọ nilu Eko

Owo yii ni Da Rocha fi da ile ifowopamọ silẹ lọdun 1907, to si di alawọ dudu akọkọ ti yoo da banki silẹ nilẹ Afirika

O dokoowo papọ pẹlu ọmọ Yoruba meji miran, Doherty ati Sedu Williams lati sagbekalẹ ile ifowopamọ ọhun, to si tun si ile ounjẹ ati okoowo kiko ẹja yinyin wọle

Korikosun ni Da Rocha ati gbajumọ elere tiata nni, Herbert Adedeji Ogunde nigba aye awọn mejeeji.

Da Rocha, olowo to n fọ asọ idọti rẹ nilu oyinbo:

Ilu oyinbo ni Da Rocha maa n fi awọn aṣọ rẹ to ba dọti ranṣẹ si lati fọ, kii si fọ aṣọ rẹ ni ilu Eko

Ojule kẹrin, opopona Tinubu ati opopona Kakawa ni ile Da Rocha wa, to si tun kọ irufẹ ẹya ile naa si orilẹede Brazil

Da Rocha nikan lo da pese omi ẹrọ lati Iju si aarin gbungbun Eko, Yaba, Ebute-Mẹtta atawọn adugbo mii ti wọn ti n poungbẹ omi ẹrọ

Ile Da Rocha nikan lo ni kangadẹrọ ati omi ẹrọ omi niwaju ile rẹ, to si maa n ta omi fawọn araalu niwaju ile rẹ

Da Rocha da gbe nigbẹyin aye rẹ ni, tori ko se igbeyawo pẹlu obinrin kankan, ti iroyin si ni o jẹ eeyan kan to le pupọ lati ba gbe inu ile

A gbọ pe lasiko kan, o ba awọn obinrin mẹta kan gbe ile lasiko ọtọọtọ, ti wọn si bimọ fun, to si bi ọmọkunrin kan ati obinrin mẹta

Lara awọn ọmọ rẹ ni Alexander Candido Da Rocha, Ẹnitan Salakọ, Louissa Ẹbun Turton ati Angelica Fọlasade Thomas

Àkọlé fídíò, A lè pe Oluwo ní Ọba ìgbàlódé kìí ṣe Ọba ìtalẹ̀mu

Da Rocha korira irọ nitori naa ko kopa ninu oselu:

Kẹkẹ ẹlẹṣin ti wọn n gun laye atijọ ni Da Rocha fi se ẹsẹ rin nigba aye rẹ, ti ko si lo awọn ọkọ bọginni rara.

Da Rocha sunmọ isejọba Gẹẹsi, o jẹ olotitọ eniyan, o korira irọ pipa, o lẹmi iwa ikora ẹni nijanu, bẹẹ ni ko lọwọ ninu oselu sise

Da Rocha bẹru Ọlọrun, ọmọ ijọ Aguda, Katoliki nii se, to si maa n fi owo rẹ se aanu fawọn alaini

Candido Da Rocha jẹ Ọlọrun nipe lẹni ọdun mejidinlaadọrun (88), ti wọn si sin si itẹ oku to wa ni Ikoyi.

Candido Da Rocha wa saye, o se aye loore, o fi owo rẹ mọ ẹbi ara, ọrẹ ati awọn ojulumọ, taa si lee pe ni olowo to n fi owo saanu laye igba tiẹ.

O lẹmi iwa ikora ẹni nijanu, to si korira irọ pipa.

Awọn abuda rere Da Rocha lo yẹ ki awa naa fi se awokọse rere, ka si tun jẹ ọmọ ti yoo sọ ọla di pupọ, dipo ka jẹ agboju logun ati akotileta.