EFCC: Yàtọ̀ sí Willie Obiano, wo àwọn gómìnà àná míì tó tó ọgbọ̀n tó kó sí gbaga

Oríṣun àwòrán, EFCC
Kìí ṣe ohun tuntun ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà pé tí gómìnì kan bá kúrò lórí oyè kí àjọ tó ń gbógunti ìwà àjẹbánú ní orílẹ̀ èdè yìí nawọ́ gán irú gómìnà bẹ́ẹ̀ láti wá wí tẹnu rẹ̀ lórí bí wọ́n bá ṣe ṣe owó nígbà tí wọ́n bá wà lórí oyè.
Gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Anambra, Willie Obiano tó fi ipò sílẹ̀ lánàá tí Charles Soludo gba ọ̀pá àṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀ ni gómìnà àná tuntun tó ti wọ gbaga àjọ EFCC báyìí lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tó kúrò nípò.
Gẹ́gẹ́ bí ìwé òfin orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ọdún 1999 ṣe là á kalẹ̀, gómìnà tó bá wà nípò ní ààbò atóbi má ṣèé báwí tabi òfin aṣẹ̀malù, èyí tí wọ́n ń pè ní "immunity".
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sé lóòtọ́ọ́ ní ọlọ́pàá yìnbọn mọ́ àgùnbánirọ̀ n'Ibadan?
- Àìsàn tó ń ṣe ọ ní ohun ṣe pẹlú oorun rẹ - Onímọ
- Báwo ní àláfíà ara Iyabo Oko, ipò wo ní ìlera rẹ̀ wà?
- Ohun tí mo fẹ́ rèé tí ìkọlù sí Ukraine yóò bá dópin - Putin
- Olùdásílẹ̀ ìjọ tí ọlọ́pàá FBI ti ń wá fọ́jọ́ pípẹ̀, kó sí gbaga EFCC lórí ẹ̀sùn wáyá-wayà
- Nàíjíríà ń sún ọjọ́ ìjà síwájú ni, mo gbà pé ìpàdé àpérò gbọdọ̀ wà - Ọba Tejuosho
- "Ọlọ́pàá ló pe mí láti wá gbé òkú Timothy Adegoke lẹ́sẹ̀ títì"
Ohun tí èyí túmọ́ sí ni pé kò sí ẹni tí ó le fi òfin gbé gómìnà tó bá wà lórí oyè, kò sí bí ìwà tí wọ́n bá wù ṣe le tóbi tó.
Àwọn gómìnà àná tí EFCC ti gbé:
Láti ìgbà tí ìjọba alágbádà tí bẹ̀rẹ̀ ní Nàìjíríà lọ́dún 1999, àwọn gómìnà àná ọgbọ̀n ní àjọ EFCC tí nawọ́ gán fún aṣemáṣe kan tàbí òmíràn, Willie Obiano ló sọ ọ́ di mọ́kànlélọ́gbọ̀n báyìí.
Àwọn náà nìyí:
Willie Obiano:
Ní ọjọ́bọ̀ ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù kẹta, ọdún 2022 ní àjọ EFCC fi póró òfin gbé gómìnà àná yìí.
Ní ọjọ́ yìí gan ló gbé ìjọba kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí gómìnà fún Gómìnà Charles Soludo.
Àjọ EFCC ní Obiano ti wà lára àwọn tí àwọn fẹ́ gbé ti pé ṣùgbọ́n òfin atóbi má ṣèé báwí tó wà lórí rẹ̀ ni kò jẹ́ kí àwọn ti gbe tipẹ́.
Ìròyìn ní àhàmọ́ ní gómìnà yìí sún lọ́jọ́ àkọ́kọ́ tó fi ipò sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí gómìnà bí ó ṣe wà ní àhámọ́ EFCC di ọjọ́ kejì.

Oríṣun àwòrán, Vanguard
James Ibori:
James Ibori ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Delta fún ọdún mẹ́jọ, ìyẹn láàárín ọdún 1999 sí ọdún 2007.
Ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́tàlá ni wọ́n sọ Ibori sí fẹ́sùn ṣíṣe mílíọ̀nù mẹ́tàdínlọ́gọ́rin dọ́là nígbà tó wà lórí oyè.
Ẹ̀sùn mẹ́wàá ni wọ́n kà sí Ibori lẹ́sẹ̀ ní ilé ẹjọ́ kan ní orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì.
Ibori sá fún ìgbẹ́jọ́ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ṣùgbọ́n ìjọba Dubai nawọ́ gan lọ́dún 2010 tí wọ́n sì fi ráńṣẹ́ sí UK láti lọ kojú ìgbẹ́jọ́ rẹ̀.
Rochas Okorocha:
Ní ilé ìgbé Rochas Okorocha tó wà ní Garki, Abuja ni àjọ EFCC nawọ́ gán an ní ọjọ́ kẹtàlá, oṣù kẹrin ọdún 2021.
Okorocha tó ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Imo láàárín ọdún 2011 sí ọdún 2019 ni wọ́n fi ẹ̀sùn kàn pé ó ṣe owó ìlú kúmọkùmọ nígbà tí ó wà nípò.
Bukola Saraki:
Lára àwọn gómìnà àná tí kò móríbọ́ lọ́wọ́ àjọ EFCC ní Bukola Saraki tí ìpínlẹ̀ Kwara.
Saraki tó tún jẹ́ Ààrẹ àná ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀ orílẹ̀ èdè yìí kó sí gbaga EFCC fẹ́sùn píparọ́ lórí dákìá kíkéde àti pípa owó ìlú ní póńpó.
Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní Saraki kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án lọ́dún 2018.

Oríṣun àwòrán, Lere Olayinka/Facebook
Orji Uzor Kalu:
Gómìnà ìpínlẹ̀ Abia tẹ́lẹ̀ rí yìí rí ẹ̀wọ́n ọdún méjìlá he fẹ́sùn ìwà àjẹbánu.
Kalu àti àwọn májì mìíràn ni EFCC fẹ̀sùn kàn pé wọ́n kó owó ìlú láàárín ọdún 1999 àti 2007 tí Kalu fi jẹ́ Gómìnà.
Pater Ayodele Fayose:
Lẹ́yìn ọjọ́ kan tí Fayose gbe ìjọba kalẹ̀ lọ́dún 2018 ló lọ fa ara rẹ̀ kalẹ̀ fún àjọ EFCC fún ìwádìí lẹ́yìn tí àjọ náà ti káde pé ó wà lára àwọn gámìnà tí àwọn yóò wádìí nígbà tó bá kurò lórí oyè.
Ìgbẹ́ja rẹ̀ ṣì wà nílé ẹjọ́ títí di òní.
Àwọn gómìnà mìíràn ni:
- Gabriel Suswam, Benue
- Audu Abubakar, Kogi
- Abdullahi Adamu, Nasarawa
- Aliyu Akwe Doma, Nasarawa
- Joshua Dariye, Plateau
- Jonah Jang, Plateau
- James Bala Ngilari, Adamawa
- Murtala Nyako, Adamawa
- Ali Modu Sheriff, Borno
- Danjuma Goje, Gombe
- Jolly Nyame, Taraba
- Sule Lamido, Jigawa
- Aliyu Wammako, Sokoto
- Abdulaziz Yari, Zamfara
- Theodore Orji, Abia
- Chimaroke Nnamani, Enugu
- Sullivan Chime, Enugu
- Ikedi Ohakim, Imo
- Godswill Akpabi, Akwa Ibom
- Diepreye Alamieyeseigha, Bayelsa
- Timipre Sylva, Bayelsa
- Lucky Igbinedion, Edo
- Olugbenga Daniel, Ogun
- Adebayo Alao-Akala, Oyo
- Rashidi Ladoja, Oyo
Ofin to n raga bo awọn gomina naa lori oye ti làá kalẹ̀ láti lè fi àwọn gómínà lára balẹ̀ láti lè gbájúmọ́ ìṣẹ́ ìlú èyí tí wọ́n gbé dání.
Fún ìdí èyí, lẹ́yìn tí àwọn gómìnà bá kúrò lórí oye, ní àwọn agbófinró tó le bí àwọn gómìnà naa ni ohunkóhun tí wọ́n bá ṣe lórí allefa.
Willie Obiano si ní gómínà àná kọkànlélọ́gbọ̀n tí àjọ EFCC yóò fi póró òfin gbé nígbà tí wọ́n bá kúrò lórí oyè,a` fẹ́sùn gbígbé owó ìlú gba oko ibòmíràn tàbí lílò ààyè náà lọ́nà tí kò tọ́.

















