High Profile Corruption Cases in Nigeria: Ajọ Transparency kẹde pé Naijiria gba ipò 150 ninu 180 niínú ìwà ajẹnánu 2022

Enikan to wa ni ahamọ

Oríṣun àwòrán, Nigeria Prison service

Lẹyin ti Ajo Transparency International kéde odiwon iwa ajébanu ti wọn pe ni 2022 Corruption Perception Index ni BBc gbe awọn iwa ibaje ti aye n pariow lori ayelujara si iranti awọn ọmọ Naijiria.

Nitori pe Index Rate International fun Naijiria ni ipo aadọjọ ninu orilẹ-ede ọgọsan ti wọn ti ṣiṣẹ iwadii iwa ibajẹ to peleke yii lo n jé ki awọn ọmọ Naijiria maa sọrọ nipa iwa ibajẹ Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Saaju asiko yii ni Alaga ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, ti kede pe ọta le lẹgbẹrin eeyan le marun un (865) ni ajọ naa fọwọ ṣinkun òfin mu laipẹ.

O ni eeyan to le ni ẹgbẹrun mẹwaa (10,152) ti wọn fẹsun kan ninu awọn afurasi naa.

EFCC , iwadii si n lọ lori ẹsun ẹgbẹrun meje ati ojilelọdunrun (7,340) ninu ẹsun ti ajọ EFCC ri gba .

Àkọlé fídíò, Nítòótọ́ mo ni ẹni tí mo ń fẹ́ tẹ́lẹ̀ kí n to pàdé Oba ṣùgbọ́n ìfaradà àti sùúrù jẹ́ kó rọ

"EFCC tun ri ọpọ owo ati dukia gba lọwọ àwọn ti aje iwa ibajẹ ṣi mọ lori,"

Alaga ajọ EFCC dupẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ naa fun iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe eyi to jẹ ki EFCC ṣe aṣeyọri .

EFCC ko ṣai fìdí rẹ mulẹ pe, ajakalẹ arun covid-19 ṣakoba fun ajọ EFCC lati ṣe ohun gbogbo to fẹ ṣe.

Awọn afurasi onijibiti

Oríṣun àwòrán, Twitter/EFCC

Amọ, jọ EFCC gbiyanju lati ṣe aṣeyọri to pọ, bo tilẹ jẹ pe idojukọ naa pọ.

O wa ṣeleri lati mu ki iṣẹ ajọ naa gbooro sii nipa ṣiṣe iṣẹ pọ pẹlu awọn agbofinro ati awọn ẹṣọ eleto abo miran.

Igbejo 2021

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ẹ wo ojú àwọn afurasí to ti rojọ́ ẹ̀ṣùn àjẹbánu sẹyin

Ileẹjọ giga julọ lorilẹede Naijiria da awọn ẹjọ to niiṣe pẹlu iwa ibajẹ awọn oloṣelu kan nu sẹyin..

Lara awọn ẹjọ ti wn pati naa la ti ri eyi ti ileẹjọ giga ni ki wọn ṣẹṣẹ bẹrẹ igbẹjọ wọn lati ibẹrẹ pẹpẹ, ati eyi ti adajọ ni ki awọn igbẹjọ wọn tẹsiwaju.

Àkọlé fídíò, Alapinni Oosa ṣàdúrà fún gogbo ọmọ kúoótù, oò jíire bí?

Lara awọn oloṣelu ti wọn ti jajabọ lọgba ẹwọn, amọ ti wọn si n koju ẹsun jẹgudujẹra miran ni Sẹnetọ to n soju ipinlẹ Abia, Uzor Kalu ati agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu PDP, Olisa Metuh.

Bakan naa ni awọn ọmọ Naijiria jankan-jankan bii Abdulrasheed Maina, Mohammed Adoke ati Doyin Akupe naa n koju ẹsun iwa ibajẹ lọwọlọwọ, ti igbẹjọ wọn yoo si tẹsiwaju.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Orji Uzor Kalu

Oríṣun àwòrán, orjikalu,com

Uzor Kalu:

Sẹnetọ Uzor Kalu lo n ṣoju ẹkun ariwa ipinlẹ Abia ni ile igbimọ Asofin agba lorilẹede Naijiria, to si tun ti jẹ gomina tẹlẹ nipinlẹ Abia.

Ọdun 2018 ni Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ, EFCC fi ẹsun kan Kalu pe o ji iye owo to le ni biliọnu meje Naira, (N7.1 billion) lasiko to jẹ gomina ipinlẹ Abia laarin ọdun 1999 si 2007.

Ẹsun oniga mọkandinlogoji ni wọn fi kan an ni ileẹjọ giga ti ipinlẹ Eko, amọ ileẹjọ to ga julọ lorilẹede da ẹjọ naa nu, ti wọn si ni ki Ajọ EFCC ṣẹṣẹ bẹrẹ igbẹjọ rẹ lati ibẹrẹ.

Àkọlé fídíò, 2020 in Retrospect: Ìjàmbá iná, ilé tó dàwó, ìwọ́de àti àrùn Covid-19 wà lára ìṣẹ̀lẹ̀ 2020

Idi ti ileẹjọ fi da ẹjọ naa nu ni wi pe, adajọ Mohammed Idris to gbọ ẹjọ naa ni oun ko ni aṣẹ mọ lori ẹjọ ọhun nitori wọn ti gbe e lọ si ileẹjọ kotẹmilọrun.

Lati igba naa ni Kalu ti kuro ni ọgba ẹwọn, to si ti bẹrẹ iṣẹ rẹ pada ni ile aṣofin orilẹede Naijiria.

Olusa Metuh

Oríṣun àwòrán, Twitter

Olisa Metuh:

Ajọ EFCC fi ẹsun kan Metuh pe o ji owo to to irinwo miliọnu Naira ni ileeṣẹ oludamọran lori eto aabo, labẹ isakoso Sambo Dasuki.

Ọdun 2016 ni wọn fi panpẹ si lọwọ, amọ to si sọ wi pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.

Ileẹjọ giga ran an lọ si ẹwọn ọdun meje, amọ Metuh gbe ẹjọ naa lọ si ileẹjọ kotẹmilọrun pe adajọ naa ko ṣe otitọ pẹlu idajọ rẹ.

Lẹyin naa ni ileẹjọ giga ni ki wọn tun igbẹjọ naa bẹrẹ, amọ EFCC ti ni awọn n lọ si ileẹjọ giga lati yi idajọ naa pada.

Doyin Akupe

Oríṣun àwòrán, Twitter

Doyin Okupe:

Arakurin Okupe to jẹ agbẹnusọ tẹlẹri fun aarẹ ana lorilẹede Naijiria, Goodluck Jonathan, ni wọn fẹsun kan pe o pin ninu owo ti wọn ji ko ni ileeṣẹ oludamọran fun eto abo ni Naijiria.

Ẹsun oniga mọkandinlọgọta ni wọn fi kan an, ti iye owo ti wọn lo lu ni ponpo naa ni miliọnu mejilelẹẹdẹgbẹrin Naira, N702milion.

Àkọlé fídíò, Caleb Adeniyi cico toys: Kò wú mi pé kí àwọn ọmọ Yoruba gbàgbé ilé àti orísun wọn

Ọdun 2018 ni wọn kọkọ tii mọle, ki wọn to gba beeli rẹ, wọn tun ti i mọle pada ni ọdun 2019.

Amọ, ileẹjọ gba laaye lati rinrinajo lọ si Ilẹ Gẹẹsi lọ gba itọju, lẹyin to lugbadi arun Coronavirus, ti agbẹjọro rẹ si ni a pada si Naijiria lati pari igbẹjọ rẹ.

Maina

Oríṣun àwòrán, Twitter

Abdulrasheed Maina:

Abdulrasheed Maina ti fi ọpọ igba sa kuro mọ ijọba lọwọ, lẹyin ti wọn fi ẹsun iwa ajẹbanu kan lasiko to jẹ Ọga Agba ajọ to n se akoso owo awọn osisẹ-fẹyinti (Pension Board) lorilẹede Naijiria.

Ajọ EFCC lo fi ẹsun kan an pe o lu owo ilu to le ni biliọnu lọna ọgọrun naira ni ponpo ni ọdun 2010 to wa ni ipo ọga agba ajọ naa.

Àkọlé fídíò, Se lootọ?: Wo irú sítàílì tó yẹ láti fi bẹ̀rẹ̀ ìbàlópọ̀ lẹ́yìn ìbímọ- Tola Ajayi

Ọdun 2013 lo kọkọ salọ kuro lorilẹede Naijiria, amọ to yọ pada wale ni ọdun 2017, ti ọwọ palaba rẹ si sege.

Lasiko igbẹjọ rẹ naa lo tun salọ kuro ni Naijiria lọ si Niger Republic ni ọdun 2020 yii, amọ ti Ajọ EFCC si tun ragba lasiko to n salọ.

Nibayii, wọn ti sun igbẹjọ rẹ siwaju.

Twitter

Oríṣun àwòrán, Twitter

Mohammed Adoke:

Ajọ EFCC fi ẹsun kan Adoke pe o pin ninu owo katakara epo rọbi Malabu oil Deal, to le ni biliọnu kan owo ile okeere.

Adoke ati onisowo kan, Aliyu Abubakar ni wọn dijọ n koju ẹsun jẹgudujẹra naa ni ileẹjọ giga ti ilu Abuja.

Àkọlé fídíò, Kayamata: Ṣé lóòótọ́ ni Kayamayo wà táwọn ọkùnrin ń lò láti wọ́nà àbáyọ sí Kayamata?

Ẹsun oniga-mẹrinla ti wọn fi kan an naa ni pe o gba owo ẹburu to le ni ọọdunrun miliọnu naira, N300milion.

Bakan naa ni wọn lo fun awọn ileeṣẹ elepo Shell, Eni ati awọn ileeṣẹ to n wa epo rọbi miran laaye, lati lu owo ilu ni ponpo lai san owo ori.

Àkọlé fídíò, Paula Gomez: ìwé Akinwumi Isola ti mo kà ni Germany lo ṣi ojú mi sí àṣà Yoruba púpọ̀