Ọ̀pọ̀ ènìyàn fara gbọta bí APC àti PDP ṣe kọlu ara wọn ní Ile-Ife

Oríṣun àwòrán, Collage
Níṣe ni ọ̀rọ̀ di bóò lọ o yà fún mi ní ìlú Ile Ife lọ́jọ́ Ajé ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù Kìíní ọdún 2023 nígbà tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP àti All Progressives Congress, APC ṣe ìkọlù síra wọn.
Ìròyìn ní onírúurú ohun ìjà olóró bíi ìbọn, àdá, àáké àti àwọn oògùn ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú méjèèjì fi ṣe ìkọlù sí ara wọn.
Kò dín ènìyàn mẹ́wàá tí wọ́n ní ó fara gba ọgbẹ́ àdá àti àáké tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì fara gba ọta ìbọn nínú ìkọlù tó wáyé fún wákàtí méjì ó lé.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ BBC lọ́wọ́, nǹkan bíi aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ ni ìkọlù náà bẹ̀rẹ̀ ní agbègbè Ita-Akogun.
Gbogbo àwọn ọlọ́jà, ọlọ́kọ̀ àti ọlọ́kadà tó wà ní agbègbè yìí ni wọ́n sá àsálà fún ẹ̀mí ara wọn láti le má fara gba ọgbẹ́ àwọn tó fa ìkọlù ọ̀hún.
Àmọ́ àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì ti ń di ẹ̀bi ẹni tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìkọlù ńlá tó sọ ìlú náà sínú hílàhílo ru ara wọn.
Bí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ń fi ẹ̀sùn kan APC pé àwọn ni wọ́n wá da ìpolongo ìbò sípò Ààrẹ àti àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin tí àwọn ń ṣe rú náà ni APC fẹ̀sùn kan PDP pé àwọn ló kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìkọlù náà.
Gbogbo àwọn tó farapa nínú ìkọlù ọ̀hún ló ti wà ní ilé ìwòsàn kan tàbí òmíràn níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú tí àwọn ọlọ́pàá sì ti dá àláfíà padà sí agbègbè náà.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù náà, igbákejì alága PDP wọ́ọ̀dù More ní Ile Ife, Segun Adefioye fẹ̀sùn kan APC pé àwọn ló wá fi àdá àti àwọn ohun ìjà olóró da ìpàdé àwọn rú.
Adefioye ní èyí ló mú kí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn náà dìde ìjà tí ọ̀rọ̀ fi di yánpọnyánrin.
Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, alága PDP ìpínlẹ̀ Osun, dókítà Akindele Adekunle ní ọ̀rọ̀ bíi wàhálà àti rògbòdìyàn kìí yẹ̀ lẹ́yìn ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó sì rọ àwọn aláṣẹ láti wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá lórí ìkọlù náà.
Agbẹnusọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ìpínlẹ̀ Osun ní tirẹ̀, Olóyè Kola Olabisi ní ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ló kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe ìkọlù sí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn kí àwọn náà tó gbọ́wọ́.
Olabisi rọ Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá láti ṣèwádìí ìkọlù náà dáradára kí wọ́n sì fojú àwọn ló lọ́wọ́ níbi ìkọlù náà winá òfin.
Agbẹnusọ Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Osun Yemisi Opalola tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ní ohun gbogbo ti padà sípò níbẹ̀.
Opalola rọ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà láti yàgò fún ìwà jàgídíjàgán kí wọ́n sì máa bá ìgbé ayé wọn lọ láì sí ìjà àti wàhálà kankan.












