Olori Sekinat Aramide Ajoke Elegushi: Nítòótọ́ mo ni ẹni tí mo ń fẹ́ tẹ́lẹ̀ kí n to pàdé Oba ṣùgbọ́n...
Èmi kìí da ọkọ mi láàmù lórí ọrọ Obinrin nítori pe O mọ ẹ̀tọ́; emi naa si mọ aaye mi ninu aye Kabiesi- Olori Elegushi
Bayii ti ọrọ awọn Olori laafin awọn Oba ile Yoruba n jade lori ayelujara lọtun losí ni BBC ṣe n jade lọ fọrọwa wọn lẹnuwo gẹgẹ bii apẹrẹ rere fun awọn ọdọbinrin asiko yii to wu wọn lati wọnu ile ọla.
Olori Sekinat Aramide Ajoke Elegushi gbalejo BBC Yoruba nilu Eko.
O sọrọ lori bi o ṣe pade Ademola Elegushi gẹgẹ bi ọrẹ lasan ti oun ko si mọ nigba naa pe yoo pada di Oba ni Eko.
O ni pe oun ni ẹni ti oun n fẹ nigba naa ati pe Kabiesio gan maa n sin oun lọ sọdọ 'Boyfriend' naa nigba naa ki ọrọ ifẹ wọn wa to pada wọ sii.
- O ní ìdí tí mo fi yan ilé Olórogún Ooni Ife dípò ilé ọlọ́kọ kan- Olori Tobi Phillips Ogunwusi
- Lẹ́yìn ti mo parí WAEC ni 1999 ni ayé gba ẹsẹ̀ lọ́wọ́ mi pẹ̀lú àlá láti ṣojú Nàìjíríà ni eré sísa
- Ẹ gbà wá o! Dókítà tó lé ní 2000 ló jápa kúrò ní Naijiria ní ọdún 2022 níkan ṣoṣo! - Ẹgbẹ́ Dokita kígbe!
- Ikú dóró! Èèyàn tó jẹ́ Ọlọ́run nípè níbi ìbúgbàmú Mọsalasi Pakistan ti di 100
- Àsìkò wo ló yẹ kí obìnrin bẹ̀rẹ̀ ìbálòpọ̀ padà lẹ́yìn ìbìmọ láìséwu?
- Wo àwọn ohun ìṣeré ọmọdé tó n kọ́ ọmọ ní èdè àti àṣà Yorùbá
- Aláàfin Adeyemi ló mú mi fẹ́ràn àṣà Yorùbá síi pẹ̀lú iṣẹ́ ìwádìí- Paula Gomez, Oyìnbó tó ń gbé àṣà Yoruba ga

Olori Aramide ṣalaye bi o ṣe pade Kabiesi Sayeed Ademola nibi ọja iya rẹ ni ṣọọbu wọn ni Isale Eko.
O sọ bi wọn se jọ bẹrẹ igbe aye irẹlẹ ninu iyara meji ki Oba Oke to sọ wọn di nla bayii bii tokotaya.
O sọrọ nipa pataki gbigba ọmọ ti Olodumare ba fun eeyan; iba ṣe ọkunrin tabi obinrin nitori pe ko si nkan ti obinrin n ṣe ti ọkunrin ko le ṣee.
Olori Aramide menuba pataki suuru ati ifarada ti ko wọpọ laarin awọn ọdọbinrin asiko yii.
O sọ nipa ajọ alaanu to da silẹ lọdun 2019 ati ohun to ṣokunda dida ajọ naa silẹ
O gba awọn ọdọbinrin to wu lati wọle ọla lati lọ kọ suuru nitori oun ko wo ipo tabi owo fẹ ọkọ nigba naa bikoṣe ifẹ ọkan oun.
- Ṣé lóòótọ́ ní Kayamata jẹ́ àdódùn àti òògùn ìbílẹ̀ tí wọn fi ń so ọkùnrin mọ́lẹ̀?
- 'Ẹ̀rú bà mí lọ́jọ́ tí mo wọ bọ́ọ̀sì dẹ́rẹ́bà ọlọ́wọ́ kan lọ Ilorin', ìrírí àwọn èrò ọkọ̀ rèé
- Ikorodu Bois: Ko si ẹni ti a kò lè sín jẹ!
- Ààwẹ̀ gbígbà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí lé ṣé àkóbá fún kíndìnrín
- Kíní yóò ṣẹlẹ̀ sí owó 200, 500 àti1000 Naira àtijó tí CBN yóò fòfin dè?