Old Naira Notes: Kíní yóò ṣẹlẹ̀ sí owó 200, 500 àti1000 Naira àtijó tí CBN yóò fòfin dè?

Oríṣun àwòrán, Others
Ni Ọjọ Kẹwaa, Oṣu Keji, ọdun 2023 ni awọn owo Naira lorilẹede Naijiria bii 200, 500 ati 1000 yoo di ohun atijọ ti wọn ko ni le lo mọ ni Naijiria.
Eyi ko ṣẹyin aṣẹ aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari fun Banki apapọ Naijiria lati sun ọjọ ti wọn yoo sun lati Ọjọ Kọkanlelọgbọn titi di Ọjọ Kẹwaa, Oṣu Keji, ọdun 2023.
Amọ ohun ti awọn eniyan ko mọ ni ohun ti yoo ṣẹlẹ si awọn owo Naira atijọ ti wọn ko ni lo mọ?
- Ìlé aṣòfin àpapọ̀ ní Naijiria tako CBN lórí ọjọ́ 10 tí wọ́n fikún àsìkò tí owó àtijọ́ yóò kúró nílẹ̀
- Ààwẹ̀ gbígbà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí lé ṣé àkóbá fún kíndìnrín
- 'Container' ṣubú lé ọkọ̀ akérò lórí nílùú Eko, èèyàn mẹ́sàn án jáde láyé
- Ìyàwó mí sọ mi dì alakisa lẹ́́yìn ìgbéyàwó wa, ẹ tú wa ká- DAUDA
- Ìdí mẹ́rin rèé tí ààrẹ Buhari fi kọ̀ lórí gbèndéke gbígba owó Naira àtijọ́..-
Kini yoo ṣẹlẹ si awọn owo Naira atijọ naa ni Ọjọ Kẹwaa, Osu Keji, ọdun 2023
Gbogbo awọn banki ifowopamọsi ni Naijiria yoo da awọn owo atijọ ti wọn ba gba pada lọwọ awọn ọmọ Naijiria pada si Banki apapọ Naijiria, CBN, ti CBN yoo si da owo wọn pada fun wọn.
Onimọ nipa eto iṣuna lorilẹede Naijiria, Qasimu Garba Kurfi ni CBN yoo da owo naa pada pẹlu Naira, ti awọn Banki ile ifowopamọsi naa yoo si da pada si awọn banki, ti awọn araalu yoo si ni anfaani lati ri owo naa gba.
Kini CBN yoo ṣe pẹlu awọn owo atijọ naa?
Onimọ nipa eto iṣuna naa ni ti owo naa ba ti de ọdọ CBN niiṣe ni wọn ba owo naa jẹ.
Qasimu Garba Kurfi ni o ni awọn eto ilana ti CBN yoo tẹle lati mọ iye owo ti wọn yoo bajẹ.
''Lẹyin ti wọn ba ti tẹle gbogbo ilana naa tan ni wọn yoo jo awọn omo naa ni ọna ti o tọ.''
Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, awọn owo tuntun ti wọn ni to tilẹ jẹ naira atijọ naa ni wọn yoo jo papọ.
Lasiko ti wọn ba n jo awọn owo naa, awọn ẹṣọ alaabo yoo wa ni kalẹ lati ri pe aabo to peye wa lasiko ti wọn ba n ba awọn owo naa jẹ.
Awọn ikọ ọmọogun Naijiria ati ikọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti Naijiria ni yoo wa nibẹ nitori naa ko ni si owo kankan ti wọn ko ni ridaju pe wọn jo.

Oríṣun àwòrán, Others
Njẹ o ṣeesẹ ki wọn sẹ atunṣe owo naa lai jo?
Ni asiko yii awọn owo ti wọn le jo ni awọn ti wọn fi rọba ṣe ti wọn n pe ni Polymer
Awọn owo naa ni 50, 20, 10 naira ati naira marun un ti wọn ṣe atunṣe rẹ (recycle) amọ jijo ni 100, 200, 500 ati 1000 naira atijọ ti wọn ba da pada.
Oṣiṣẹ agba banki tẹlẹri to ba BBC sọrọ ni igba de igba ni CBN ma n jo awọn owo ti ko dara ati eleyii to ba ti bajẹ.
Awọn wo lo ni aṣẹ lati ba owo Naira jẹ?
Labẹ ofin Naijiria, CBN nikan lo ni aṣẹ lati jo owo ni ina lẹyin ti wọn ba ti sọpe ko dara mọ abi ko wulọ mọ ni Naijiria
''Ẹnikẹni to ba jo owo tabi baa jẹ lai gba aṣẹ lọwọ CBN yoo padanu owo rẹ, nitori CBN nikan ni ofin Naijiria ro lagbara lati sẹ atunṣe owo tabi baa jẹ.''
















