'Ọwọ́ wá ti tẹ àwọn tó ń tà owó náírà tuntun, bí wọ́n ṣe kó sí wa lọ́wọ́ rèé'

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Latari awọn iroyin to gbòde kan lori bi awọn ọmọ Naijiria kan ṣe ti n na obitibiti owo naira tuntun yala-yolo nibi ìnáwó, to si jẹ wipe owo ọhun gan ko tii kari gbogbo araalu to nilo pasiparọ rẹ, ọwọ ṣikun òfin ti tẹ àwọn afurasi kan to sọ titanka owo naa di katakara ara wọn ti wọn fi n pa owo sapo.
Gẹgẹ bi ọrọ ti agbẹnusọ àjọ ọtẹlẹmuyẹ, Ọjọ gbọn Peter Afunaya fi sita lọjọ Aje, ó fidi rẹ múlẹ̀ pe kódà, awọn oṣiṣẹ banki kan ń dana sábẹ́ ìwà to n ba ọrọ aje jẹ yii. Àjọ naa ti wa fà àwọn to n ta owo naira leti pe ki wọn jawọ ninu iwa ibajẹ naa.
Bákan náà ni DSS tun rọ awọn Ileeṣẹ alamojuto ọrọ yii lati dìde si ṣíṣe amojuto to péye lati fòpin si iwa tuntun to gbòde yii.
Gomina Banki Apapọ CBN sọrọ

Oríṣun àwòrán, CBN
Ẹwẹ, Gomina Banki àpapọ̀, Godwin Emefiele ti toju bọ ọrọ naa to si ni oun tún ti ṣepade pẹlu awọn ajọ to n ri si iwa jẹgudujẹra, EFCC, ICPC ati Ọga àjọ ọtẹlẹmuyẹ ọrọ to ni ṣe pẹlu ọwọ ti gbogbo wọn si ti fẹnu ko wipe awọn yóò kọ́kọ́ rii daju pe ṣíṣe pasiparọ owo tuntun naa n waye bo ṣe tọ ni ibamu pẹlu òfin.
Afunaya fi lede pé àjọ DSS ti pàṣẹ fun gbogbo awọn ẹka ati igun to rọ mọ Ileeṣẹ wọn kaakiri láti rii daju pe wọn fi ẹnikẹ́ni tabi ẹgbẹ́ to ba n lọwọ ninu ohun aibofin mú yìí hande.
Àjọ náà wá rọ àwọn aráàlú tó bá keefin awọn to n ta owo lati ta awọn àláṣẹ to tọ lolobo nípa wọn.
Bákan naa ni Gomina ile ifowópamọ to ga julọ sọ pe awọn ti fi fidio kan sọwọ́ si àjọ EFCC tí wọn yóò si fi imu ẹnikẹ́ni ti wọn ba ri danrin.
Ìlé aṣòfin àpapọ̀ ní Naijiria tako CBN lórí ọjọ́ 10 tí wọ́n fikún àsìkò tí owó àtijọ́ yóò kúró nílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Ile aṣofin apapọ lorilẹede Naijiria ti kede pe awọn tako ikede Banki apapọ Naijiria pe awọn ti fi ọjọ mẹwaa kun gbedeke lati ko owo atijọ kuro nilẹ.
Awọn aṣofin naa ni awọn duro lori ọrọ ti wọn kede pe Oṣu Kẹfa ọdun yii ni ki Banki apapọ Naijiria fi gbedeke naa si ki o le mu irọrun ba awọn ọmọ Naijiria.
Saaju ni adari Banki apapọ ni Naijiria, Godwin Emefiele ni owo naira to wa lọwọ awọn eniyan ko pọ mọ, ati pe ida marundinlọgbọn ni nitori naa ọjọ mẹwaa to fun wọn lati da owo naa pada.
Amọ awọn aṣofin ni iye ọjọ naa ti kere ju, ti ọpọ yoo si di alaini ti ijọba koba sun gbedeke naa si iwaju.
Awọn aṣofin fi aidunnu wọn han si igbeṣẹ CBN
Sẹnetọ Uba Sani to jẹ alaga ile aṣofin lori ọrọ banki ni igbesẹ CBN yii ko gba aṣẹ awọn aṣofin
Sani ni ọjọ mẹwaa naa ti kere ju lati da awọn owo atijọ pada, ti wọn si ni oṣu mẹfa ni awọn araalu nilo ki o le rọrun fun wọn.
Awọn aṣofin naa ni idi ti awọn fi gbe igbesẹ naa ni nitori aisi owo to gbode kan ati awọn araalu ti wọn n gbe ni agbegbe ti ko si Banki nibẹ, eyi yoo fi iya jẹ awọn eniyan.
Wọn tun fikun un pe awọn ti wọn tilẹ ni apo iṣuna si Banki ko i tii raye da owo pada nitori ọpọ ero ti wọn n lọ si banki ni ojoojumọ lati da owo pada.
Bakan naa ni wọn kesi awọn gomina lati sẹpade pẹlu aarẹ Buhari lati le ri bi iṣoro naa yoo ti pọto fun awọn araalu.
Wọn ni adari CBN ko ni gbe igbese kan lai gba aṣẹ lọwọ aarẹ orilẹede Naijiria, nitori naa ni wọn ṣe kesi awọn gmina lati se ipade pẹlu aarẹ Buhari.
Awọn aṣofin naa wa kesi adari ileeṣẹ banki apapọ Naijiria lati ṣe ojuṣe wọn nipa titẹle ofin to de wọn ni ẹka CBN act, Awọn aṣofin fi aidunnu wọn han si igbeṣẹ CBN
CBN kéde afìkún àsìkò tí owó àtijọ́ yóò kúró nílẹ̀

Oríṣun àwòrán, @CBN
Gomina Banki Naijiria, Godwin Emefiele ti kede pe ijoba ti fi kun gbendeke asiko ti won yoo ko owo atijo kuro nile.
Emefiele ṣalaye pe lẹyin ọpọlọpọ ipade pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari ni wọn pinnu lati fi kun iye ọjọ ti wọn yoo ko owo naa kuro nilẹ.
Saaju ni wọn ti kede ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kinni, ọdun 2023 gẹgẹ bi ọjọ to gbẹyin ṣugbọn bayii, wọn ti sun un siwaju di ọjọ kẹwaa, oṣu keji, ọdun 2023.
Emefiele dupẹ lọwọ Buhari fun atilẹyin to sẹ fun un lasiko to n gbe igbesẹ akọni yii .
Emefiele tun salaye pe o ti to ida 75% ninu ọgọrun un owo atijọ to ti wọle bayii
Ati pe oun gbe igbesẹ naa ki odiwon iye nkan ti owo naira le ra ati agbara rẹ le gbe pẹẹli sii ni.
O ni yoo tun dena agbara owo ti awon ajinigbe n gba bii owo itusilẹ ni eyi ti yoo ran awon oṣiṣẹ alaabo lọwọ lati maa ri wọn mu lasiko.
Ojọ kẹwaa, oṣu keji ọdun yii ni wọn ko ni le maa na owo atijọ mọ nigboro Naijiria.
Emefiele sọ pe awọn ti ri 1.9 tirillion ninu 2.7 trillion to ha sita gba wọle pada ni Naijiria bayii.
Emefiele sọ pe to ba tun ti di ọjọ kẹwaa, oṣu keji si ọjọ kẹtadinlogun, oṣu keji, ọdun 2023 yii ni awọn eeyan ṣi ni oore ọfẹ lati paarọ owo atijọ wọn si tuntun ni banki Naijiria apapọ ti a mọ si Central Bank of Nigeria.
Ọṣe kan ni CBN tun ya kalẹ lati ṣe paṣipaarọ owo naa titi yoo fi kasẹ nilẹ tan leyin asiko gbendeke tuntun yii












