Yóò ṣòro fún ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn láti yí ìdájọ́ tó yọ Adeleke kúrò nípò gómìnà padà – Falana

Oríṣun àwòrán, @IfedolapoOsun
Agbẹjoro agba Naijiria, Femi Falana ti sọ pe o yẹ ki awọn oludibo nipinlẹ Osun pe ajọ eleto idibo, INEC, lẹjọ lori pe o fi ibo wọn ṣofo.
Falana lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin Arise.
Ọrọ yii lo n jade lẹyin ti ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye esi ibo gomina ipinlẹ Osun to waye ninu oṣu Keje ọdun to kọja kede pe Gboyega Oyetola lo jawe olubori ninu eto idibo naa.
Ile ẹjọ ọhun ni iye ibo ti wọn ka fun gomina Ademola Adeleke pọ ju iye oludibo to wa lawọn ibudo idibo bii ẹẹdẹgbẹrin lọ.
Lẹyin naa ni ile ẹjọ ọhun paṣe ki INEC gba ipo gomina naa lọwọ Ademola Adeleke, ko si gbe fun Gboyega Oyetola fun saa keji.
Yoo ṣoro lati yi idajọ naa pada nile ẹjọ kotẹmilọrun
Falana sọ pe “Ohun to yẹ ki awọn oludibo lagbegbe yẹn ṣe ni ki wọn pe INEC lẹjọ pe INEC fi ibo wọn ṣofo.”
Gẹgẹ bii ohun to sọ, yoo ṣoro fun awọn agbẹjọro Adeleke lati yi idajọ to wa nilẹ pada ti wọn ba de ile ẹjọ kọtẹmilọrun.
O ni “Bi mo ṣe n wo idajọ yii, mo gbagbọ pe yoo ṣoro lati yi idajọ naa pada.”
“Ori INEC lo yẹ ki wọn ti fọ agbọn ohun to ṣẹlẹ.”
“O yẹ ki INEC pada lọ tun ero rẹ pa ki irufẹ nnkan bayii ma baa waye mọ.”
“Nitori ti irufẹ nnkan bayii ba waye ninu eto idibo Aarẹ, o le da rugudu ti apa INEC funra rẹ ko ni ka.”
Ẹwẹ, Ademola Adeleke ti ile ẹjọ ni ki wọn gba ipo lọwọ fun Oyetola ti sọ fun awọn alatilẹyin rẹ ki wọn ma fa wahala kankan nitori oun yoo gba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ.
Amọ ṣa, awọn alatilẹyin rẹ kan ti ṣe ifẹhonuhan niluu Osogbo lopin ọsẹ.












