Wọ́n yẹgi fún ọ̀dọ́kùnrin mẹ́rin ní Iraq lẹ́yìn rògbòdìyàn tó bẹ́ sílẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ Ijab

Oríṣun àwòrán, WANA/REUTERS
Wọn ti yẹgi fun ọdọkunrin mẹrin ni Iraq lẹyin ifẹhonuhan to gba orilẹ-ede naa kan loṣu mẹrin ṣeyin, nigba ti wọn ṣedajọ iku fun eeyan mejidinlogun mii.
Awọn ajọ ajafẹtọ ọmọniyan sọ pe igbejọ awọn eeyan naa ko lẹsẹ nilẹ.
Aarin ọjọ márùndínláàdọ́rin pere ti wọn fi ṣikun ofin mu ọkan lara awọn eeyan naa, Mohammad Mehdi Karami to jẹ ẹni ọdun mejilelogun, ni wọn yẹgi fun un.
Awọn eeyan ilẹ naa sọ fun ileeṣe iroyin BBC pe iṣeju marundinlogun pere lo ni lati gbeja ara rẹ nile ẹjọ.
Eredi ifẹhonuhan to mi Iraq titi
Ifẹhonuhan naa bẹrẹ lẹyin iku ọdọbinrin Mahsa Amini, ẹni ọdun mejilelogun ti ọlọpaa Sharia ti mọle nitori ko wọ ijaabu.
Awọn alaṣẹ ilẹ naa gbiyanju lati pana ifẹhonuhan ọhun, eyii to mu ki wọn fi ṣina ibọn bolẹ fun awọn olufẹhonuhan.
O kere tan, eeyan 481 ni awọn ologun ṣekupa lasiko ifẹhonuhan ọhun.

Oríṣun àwòrán, WANA/REUTERS
Wọn ti Karami mọle lori ẹsun pe o lọwọ ninu iku ọkan lara awọn agbofinro to n gbiyanju lati pana iwọde naa.
Ofin Iran gba awọn afurasi laaye lati yan agbẹjọro wọn, amọ nigba mii ijọba ni yoo yan agbẹjọro fun wọn ti ẹsun ti wọn fi kan wọn ba buru jọjọ.
Lasiko igbẹjọ ọdọkunrin yii, wọn ko gba awọn akọroyin atawọn mọlẹbi rẹ laaye lati wa ninu ile ẹjọ.
Nigba ti yoo fi di ọjọ karun un, oṣu Kejila, wọn ti ṣedajọ iku fun Karami pẹlu awọn mẹrin mii ti wọn jọ n jẹjọ.
Baba rẹ, Mashaalah Karami sọ fun ileeṣẹ iroyin Etemad Newspaper pe ọmọ naa lo pe oun lati jabọ pe wọn ti dajọ iku fun oun.
O ni “O pe mi lori aaago pe, baba mi, wọn ti ṣe idajọ wa o, idajọ iku ni wọn fun mi, amọ ẹ maṣe sọ ohunkohun fun mama mi.”
Wọn fiya jẹ mi ninu atimọle

Oríṣun àwòrán, WANA/REUTERS
Ile ẹjọ tun paṣẹ pe ki wọn yẹgi fun Seyed Mohammad Hosseini, to jẹ ẹni ọdun mọkandinlogoji lori ẹsun kan naa ti wọn fi kan Karami.
Ko si obi rẹ kankan laye mọ amọ o gbiyanju lati gba agbẹjọro lẹyin ti ile ẹjọ to ga julọ sọ pe wọn gbọdọ yẹ igi fun.
Agbẹjọro rẹ, Ali Sharifzadeh Ardakani ṣalaye pe ṣe lo n wa ẹkun mu lasiko ti oun ṣabẹwo si lọgba ẹwọn.
O ni “Ni ṣe lo n wa ẹkun mu, o sọ nipa bi wọn ṣe fi iya jẹ oun lọna aitọ.”
“O fi kun pe wọn di oun lọwọ-lẹṣẹ ti wọn si n na oun.”
Ni igbẹyingbẹyin, wọn yẹgi fun Hosseini lọjọ keje, oṣu Kini, ọdun 2023 yii.












