Ọmọ ọdún mẹ́tàlá ló wà ní ìdí ìkọlù tó wáyé ní Jerusalem

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ileeṣẹ ọmọogun lorilẹede Israel ti ni ọmọ ọdun mẹtala lati Palestine lo wa ni idi ikọlu to waye ni ilu Jerusalem ni Ọjọ Satide, Ọjọ Kejidinlọgbọn, Osu Kini, ọdun 2023.

Awọn meji lo farapa ninu iṣẹlẹ naa- baba ati ọmọ ni wọn farapa yanayana ti wọn si n gba itọju lọwọ ni ileewosan.

Awọn mejeeji ni ọmọ ọdun mẹtala naa ṣekọlu si lasiko ti wọn n lọ lai tọ ẹnikẹni.

Ileeṣẹ ọloogun ni awọn yinbọn lu ẹni to ṣekọlu naa si awọn ti wọn n lọ jọsin ni ti wọn.

Eyi n waye lẹyin ti eniyan meje ku ti eniyan mẹta si farapa nigba ti awọn kan sẹkọlu si awọn to n lọ si ile ijọsin Synagogue ni agbegbe ila oorun Jerusalem.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn mejilelogoji ni awọn ti fi panpẹ ọba mu lori iṣẹlẹ naa.

Ikọ ọmọogun ilẹ Israel ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni ọdọmọde to ṣekọlu naa kan tete ṣekọlu si awọn marun un ti wọn n lọ si ile ijọsin ti meji ninu wọn si wa ni ileewosan pajawiri lọwọlọwọ.

Wọn si ṣapejuwe ikọlu naa gẹgẹ bi eleyii to buru jai lasiko yii.

Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye...

Awọn olujọsin ni ilẹ Israel korajọpọ lati gbadura ni Ọjọ Sabbath ni iu synagogue ni ilu Neve Yaakov.

Wọn n jade lati ile ijọsin ni agbebọn naa da ibọn bo wọn ni ọsan gangan.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn yinbọn pa agbebọn naa.

Ikọ agbesunmọmi ilẹ Palestine gboriyin fun ẹni to ṣekọlu naa , bi tilẹ jẹpe wọn ko kede boya ara wọn ni.

Iṣẹlẹ ikọlu si ara w n bẹrẹ nigba ti ikọ ọmọogun ilẹ Israel ṣekọlu si agbegbe occupied West Bank ti eniyan mẹsan an si ba iṣẹlẹ naa lọ.

Lẹyin naa ni wọn ju ado oloro lati Gaza si Israel , ti israel naa si ju odo oloro pada si wọn.

Ọjọ Ayajọ Halocaust Memorial Day ti wọn n ṣe ayajọ ti awọn Nazi pa awọn Juu miliọnu mẹfa ni orilẹede Germany.

Awọn adari ni agbaye fesi si iṣẹlẹ naa

Aarẹ orilẹede Ukraine, Aarẹ Volodymyr Zelensky ti bu ẹnu atẹ lu ikọlu naa, to si ni ọkan lara awọn to farapa ninu iṣẹlẹ naa jẹ arabinrin lati ilẹ Ukraine.

Ninu ọrọ rẹ aṣoju minisita fun ọrọ ilẹ okeere, James Cleverly loju opo Twitter bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa, ti wọn si ṣọpe awọn sẹ atilẹyin fun awọn ara ilẹ Isrẹli.

Bakan naa ni aarẹ orilẹede Amẹrika, Joe Biden kesi adari ilẹ Israel, Benjamin Natanyahu lati ba wọn kẹdun, ki wọn si fi atilẹyin wọn han fun awọn ara ilẹ naa.

Ninu ọrọ wọn, ileeṣẹ ikọ ọmọogun Israel ni awọn yoo fikun un ikọ ọmọogun awọn to wa ni agbegbe West Bank.

Agbegbe naa ni wọn ti ilẹ Palestine ati Israel ti n ja si fun ọpọlọpọ ọdun, ti o si ti fa ikọlu laarin ilẹ mejeeji.