Ìyàwó mí sọ mi dì alakisa lẹ́́yìn ìgbéyàwó wa, ẹ tú wa ká- DAUDA

aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Aarẹ ile ejo abẹlẹ to wa ni Mapo, Ibadan, Ipinlẹ Oyo, Iyaafin S.M Akintola, ti gbo eri ọkunrin kan, Dauda Adele ti o ro ile ẹjọ lati dajo ikọsilẹ laarin oun ati iyawo rẹ, Bisola Adele, nitori wi pe wahala re po ti os feran ija nigbagbogbo.

 Gẹgẹbi Dauda ṣe so,Bisola kuro ni ile rẹ ni ọdun meji sẹhin.

 Bayi Dauda rawọ ẹbẹ si ile-ẹjọ lati tu igbeyawo wọn kaa.

Ninu awijare re Bisola tako ẹsun ti ọko rẹ fi kan an, kọ si gba ki ọkọ rẹ ni akoso awọn ọmọ wọn.

 Dauda ninu awijare rẹ ni,igbeyawo oun ati Bisola lodi si ifẹ awọn obi Bisola nitori wọn kọ nifẹ oun.

Dauda mi awọn obi Bisola doju ija kọ ajọṣepọ to wa laarin oun ati ọmọ wọn,sugbọn nitori ifẹ ti oun ni si Bisola awọn ṣe igbeyawo.

Dauda tẹsiwaju wí pe oun ko san owo ori Bisola nitori awọn ẹbi Bisola kọ daasi awọn lakoko igbeyawo.

O ni Bisola ni irele bí aguntan sugbọn lẹyin igbeyawo ni Bisola yaa ẹhanna ti ko si fi ọwọ woo oun gẹgẹ bi ọkọ.

O ni ọrọ Abisola di abẹrẹ ti ko ni okun nìdí nitori oun ko le fe jọ rẹ sun awọn obi rẹ,Dauda fikun pe ojojumo ni ija maa n waye laarin oun ati Abisola ti alafia ti jina silẹ wọn.

aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Oro ile ẹjọ layi fopin si igbeyawo naa nitori Bisola ti sọ oun di alakisa nitori wi pe gbogbo aṣọ oun n9 Bisola ti faya nigbakigba ti awọn bá ní ariyanjiyan.

Dauda ni Bisola lọ fún ra rẹ kò jade lẹyin igba ti o fẹ bàa aaye oun jẹ.

Aarẹ ile abẹẹlẹ na sun igbejo lori ẹsun naa di ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu keji ọdun yii

n fun igbejo siwaju sii.