Mo fẹ́ fẹ ọkọ míì lẹ́yìn tí mo di opó ṣùgbọ́n àwọn ọmọ mi bẹ̀ mí pé àwọn yóò ṣe ọkọ fún mi- Mama G

Oríṣun àwòrán, others
Agba oṣere tiata Nollywood Patience Ozokwor, ti ọpọ si Mama G, ti tu kẹkẹ ọrọ lori idi ti ko fi fẹ ọkọ miiran lẹyin to padanu ọkọ rẹ.
O ni oun gbe igbesẹ naa nitori awọn ọmọ oun ṣe ileri lati ṣe ọkọ fun oun lẹyin ipapoda Baba wọn.
Ozokwor sọ sọrọ yii nigba to n darapọ mọ agba oṣere tiata miiran, Mercy Johnson lori ifọrọwerọ kan lori ayelujra.
“Mo fẹ lọkọ miiran sugbọn awọn ọmọ mi bẹ mi lati maa ṣe gbe igesẹ naa nitori ti wọn, ti wọn si ṣe ileri pe awọn yoo ṣe ọkọ fun mi.
“Wọn ni ki wa pẹlu awọn nitori ki awọn ọrẹ wọn le maa fiwọn ṣe yẹyẹ pe pẹlu ọjọ ori wọn, iya wọn tun lọ lọkọ miiran, ti mo si gba siwọn lẹnu pẹlu bi o ṣe jẹ pe iwa imọ tara ẹni nikan ni wọn wu.
“Mo gbe igbesẹ naa fun wọn, fun mọlẹbi mi.
Ozokwor tẹsiwaju lori idi to fi dẹkun wiwọ ẹgba sọrun ati lilo atike.
O ni ọmọ oun ọkunrin ni Ọlọrun ran si oun nigba to ni ala lori bii Ọlọrun ṣe fẹ ki oun gbe igbesẹ aye oun.
“Ọmọ mi ọkunrin ni Ọlọrun lo fumi, igba meji ni o ni ala pe Ọlọrun ni oun fẹran mi bi o ṣe dami ju igba ti n ba tun ara mi da lọ, nigba to ma ni ala naa ni ẹlẹkẹta, mo mọ pe moni lati fi opin si.”
Mama G ló bá mi sọ̀rọ̀ tí mo fi dẹ́kun aṣọ ìwọ̀kúwọ̀ kí n lè jẹ́ àpẹrẹ rere fáwọn ọmọ mi- Mercy Johnson

Oríṣun àwòrán, Mercy's Menu
Oṣere tiata Hollywood, Mercy Johnson ti salaye bi agba oṣere tiata Patience Ozokwor ṣe gba nimọran lati dẹkun wiwọ asọ iwọkuwọ nitori pe oun yoo bimọ nijọ kan.
Ninu ifọrọwerọ ọhun, Ozokwor ni pe ṣe Mercy ranti igba to oun gba a nimọran lori asọ wiwọ nitori ọjọ ọla awọn ọmọ rẹ.
“Ṣe o ranti nigba ti o si kere, ko to lọkọ, ti mo sọ fun rẹ pe awọn aworan to ya loni ni yoo ṣe apejuwe igbesi aye to gbe fun awọn ọmọ rẹ.
“Awọn ọmọ rẹ yoo ri awọn aworan yii ni ọjọ ọla, lẹsẹkẹsẹ ni wọn yoo mọ iru igbesi aye to gbe.”
Johnson fesi pada pe oun ranti
“Bẹẹni mo ranti pe ẹ sọ pe Mercy ma mura daadaa, wa bimọ, ti awọn ọmọ rẹ ba dagba , wọn yoo bi ẹ pe kilode to mura bayi.
“Mo ranti, ori komi yọ sugbọn mo kọgbọn ni ọna to nira.”















