Ǹjẹ́ ìjọba àpapọ̀ ti fowó kún owó epo bẹntírò?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti kede pe awọn ti ṣe afikun si owo epo bentiro pẹlu ida mẹsan ku diẹ, (8.8%), ti wọn si ti bẹrẹ si ni maa ta ni owo toto marundinlaadọwa naira nipinlẹ Eko ati ọkoolenigba naira ni awọn ipinlẹ yooku.
Olori awọn ileeṣẹ alaadani epo bentiro nipinlẹ Kano, Bashir Danmallam lo fi ọrọ naa mulẹ fun BBC, o ni awọn ti gba asẹ lọwọ ijọba apapọ.
O tẹsiwaju pe ipinlẹ Eko yoo ma ta epo bentiro wọn marundinlaadọwa naira (N185) fun jala epo kan, ti awọn ipinlẹ yooku ni guusu iwọ oorun yoo si ma ta ti wọn ni mẹwadinlugba naira (N190).
Danmallam ni ko ki n ṣe ohun iyalẹnu pe ki ijọba apapọ to kede afikun naa, pupọ awọn ile epo bentiro ni wọn ti fi owo kun owo epo bentiro ni owo to yatọ si nnkan ti ijọba gbe kalẹ.
Bakan naa ni ri awọn ile epo miiran to ti kogba wọle nitori bi epo bentiro ṣe safẹrẹ lorilẹede Naijiria.
Ikede afikun owo epo bentiro lo waye lẹyin ti minisita fun eto isuna, Zainab Ahmed fidi rẹ mulẹ pe o ṣeṣe ki ijọba apapọ yoo owo iranwọ sọbusídi kuro ninu oṣu kẹrin ọdun 2023.
Yiyọ owo iranwọ sọbusidi lorilẹede Naijiria ni o ti dape yoo wa si imusẹ latari awọn oludije sipo aarẹ ṣe n tẹnumọ pe awọn yoo gbe igbesẹ naa nitori awọn ko nri anfani to n ṣe.











