Ìjọba kéde ọjọ́ méje fún ìdárò ikú ìgbákejì ààrẹ

Aworan

Oríṣun àwòrán, AFP

Aarẹ orilẹede Gambia, Adama Barrow ti kede ọjọ meje lati ṣe idaro iku igbakeji aarẹ orilẹede naa, Badara Alieu Joof.

Igbakeji aarẹ naa ku ni ẹni ọdun mẹrindinlaadọrin.

Ijọba ni ọkunrin naa dagbere fun aye lẹyin aisan ranpẹ.

Awọn araalu tilẹ ro pe igbakeji aarẹ naa n gba itọju ni ile iwọsan ni, ti ijọba ilẹ naa kosi sọ nkankan nipa rẹ.

Nibayii, ijọba ni wẹrẹ ti wọn ba ti gbe oku rẹ kuro ni ileewosan ni wọn yoo tẹ si Ile igbimọ aṣofin orilẹede naa.

Wọn ko i tii sọ nipa ọjọ ti wọn yoo ṣe isinku igbakeji aarẹ naa.

Ijọba ṣe apejuwe arakunrin Joof gẹgẹ bi onimọ to fi gbogbo aye rẹ wa bi igbeaye irọrun yoo ṣe wa fun araalu.

Tani igbakeji aarẹ orilẹede Gambia to papoda?

  • Arakunrin Badara Alieu Joof jẹ̀ onimo nipa oṣelu, ti wọn si bi ni ọdun 1957.
  • Ọdun to kọja lo bẹrẹ iṣẹ ilu gẹgẹ bi igbakeji aarẹ.
  • Joof lọ si ileẹkọ Armitage High School lẹyin lo lọ si ileẹkọ awọn tisa ni agbegbe Yundum.
  • O kẹkọ imọ eto ẹkọ ni Fasiti Bristol, ko to lọ si University of London fun masters rẹ.
  • Lẹyin naa lo tun kẹkọ imọ eto idagbasoke oro aje, iyen development Economics ni ileẹkọ fasiti Bath ni Ilẹ Gẹẹsi.
  • Joof ṣiṣẹ ni Banki agbaye lati ṣoju ilẹ Gambia to si ṣiṣẹ pẹlu Mariama Sarr-Ceesay.
  • Ọdun 2017 ni aarẹ Adama Barrow yan si ipo gẹgẹ bi Minisita to n risi eto ẹkọ giga ni orilẹede ọhun.