Olóòtú ìjọba New Zealand fẹ́ kọ́wè fi ipò sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Olootu ijọba orilẹ-ede New Zealand, Jacinda Ardern, ti kede pe oun yoo kuro ni ipo to ba di oṣu to n bọ.
Arabinrin Ardern sọ pe ‘agbara oun ko to’ mọ lati dari, eyi ti yoo mu ko fi ipo silẹ gẹgẹ bi olori ẹgbẹ oṣelu Labour titi ọjọ keje, oṣu Keji, ọdun 2023.
Ṣugbọn wọn o ti dibo yan ẹni ti yoo rọpo rẹ ṣaaju ọjọ naa, botilẹ jẹ pe ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa, ni idibo gbogboogbo yoo waye.
Arabinrin Ardern, ẹni ọdun mejilelogoji sọ pe oun ti ronu si ọjọ iwaju oun.
O ni iṣẹ naa ko rọrun fun oun lati bi ọdun mẹfa to ti wa lori aga iṣakoso.
Ardern ni olori orilẹ-ede ti ọjọ ori rẹ kere julọ, nigba to fi di olootu ijọba New Zealand lọdun 2017, lẹni ọdun mẹtadinlogoji.
Ọdun kan lẹyin rẹ, o tun di olori orilẹ-ede keji to bimọ lori ipo.
Botilẹ jẹ pe ẹgbẹ oṣelu rẹ bori ninu idibo ọdun 2020, awọn eeyan ko fi bẹẹ gba tiẹ mọ l’abẹle lati oṣu diẹ sẹyin.
Ṣugbọn o ni oun ko kọwe fi ipo silẹ nitori pe oun lero pe ẹgbẹ oṣelu Labour ko le wọle ninu idibo. O ni oun ṣe bẹẹ nitori pe oun gbagbọ pe wọn yoo bori.
“A nilo awọn ejika tuntun to le ru ẹru, fun awọn ipenija wa.”
Igbakeji olori, Grant Robertson sọ pe oun ko ni i dije dupo fun ipo olori ẹgbẹ naa ti yoo waye lọjọ Abamẹta.
Lara awọn aṣeyọri ti Arabinrin Jacinda ni ijọba oun ṣe aṣeyọri ninu rẹ ni amojuto ayipada oju ọjọ, ipese ile gbigbe ati adinku ba iṣẹ ati oṣi to n ba awọn ọmọde finra – eyi to ni o jẹ nkan iwuri fun wọn.
O ni amọ oun ni ireti pe awọn ọmọ orilẹ-ede New Zealand yoo ranti oun gẹgẹ bi “ẹlẹyinju aanu”.












