Mínísítà,èèyàn mẹ́tàdínlógún mìí kú nínú bàálù tó já ní Ukraine

Ukraine

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ko din ni eeyan mejidinlogun to ku lẹyin ti baalu ẹlikọpita kan já nitossi ile itọju ọmọ wẹwẹ kan niluu Kyiv, Ukraine.

Minisita fun ọrọ abẹle, Denys Monastyrsky naa wa lara awọn eeyan to ku. Oun pẹlu eeyan mẹjọ miran lo wa ninu baalu naa nigba to ja.

Ni kete ti baalu ẹlikọpita naa jabọ, ni ina sọ.

Ọmọde mẹta wa lara awọn to ku, eeyan mẹẹdogun mii si n gba itọju nileewosan.

Yatọ si minisita Monastyrsky, igbakeji rẹ, Yevhen Yenin ati akọwe fun ijọba orilẹ-ede Ukraine, Yurii Lubkovich, naa ku ninu ijamba naa.

Monastyrsky, ẹni ọdun mejilelogoji jẹ pataki ninu iṣejọba Aarẹ Volodymy Zelensky, o si ko ipa to jọju ninu fifi iroyin sita nipa iye eeyan ti awọn ado oloro Russia ba lati oṣu Keji, ọdun 2022 to ti n gbogun ti Ukraine.

Ọga agba ọlọpaa orilẹ-ede naa, Ihor Klymento sọ lori Facebook pe ileeṣẹ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri lo ni baalu naa.

Denys Monastyrsky

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Denys Monastyrsky

Monastyrsky, ni ọga agba ninu ijọba to ti i ku lati igba ti ogun Russia ti bẹrẹ, botilẹ jẹ pe ko tii si apẹẹrẹ kankan to tọka si pe ijamba naa kii ṣe oju lasan.

Oludari kan nileeṣẹ aarẹ, Kyrylo Tymoshenko sọ pe minisita naa n lọ si oju ogun kan, ni baalu rẹ jabọ.

Oludamọran kan nileeṣẹ ọrọ abẹle, Anton Herashchenko sọ pe ọrẹ ni awọn ọkunrin mẹtẹẹta, ti wọn si ṣiṣẹ fun takuntakun lati ro Ukraine l’agbara.