Ọkọ̀ Kunle Afod jóná, àwakọ̀ rẹ̀ farapa yánna-yànna

Bọọsi to jona

Oríṣun àwòrán, screenshot/kunle afod

Agba oṣere, Kunle Afod ti kede pe adanu nla kan ba oun lọjọ Aje, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kinni.

Ninu ọrọ kan to kọ si ori ayelujara Instagram rẹ ni Ọgbẹni Afod ti sọ pe ọkọ bọọsi kan to jẹ ti ẹ jona.

Ṣaaju lo ti kọkọ fi ọrọ kan sita, eyi to fi n sọ pe ko yẹ ki iru ajalu naa ṣẹlẹ si oun niru asiko yii.

Ni kete to fi sita si ni awọn akẹẹgbẹ rẹ ati awọn ololufẹ rẹ ti n ba a kẹdun.

Lẹyin naa lo pada fi fidio ọkọ bọọsi naa sita.

Fidio naa ṣafihan bọọsi funfun naa ti inu rẹ jona, paapaa ni iwaju nibi ti awakọ n joko si.

Ọkọ naa jọ pe Afod fi n ṣiṣẹ sinima yiya ni, nitori pe wọn so asia fiimu kan mọ iwaju rẹ.

Ajoku ọkọ bọọsi naa

Oríṣun àwòrán, screenshot/kunle afod

Bọọsi to jona

Oríṣun àwòrán, screenshot/kunle afod

Ọgbẹni Afod sọ pe ni aarọ ọjọ Aje ni iṣẹlẹ naa waye.

“Ni aarọ oni ni bọọsi mi jona. Awakọ to wa a jona pupọ.”

Bakan naa lo sọ pe ọkunrin kan to gbiyanju lati ṣe iranlọwọ nigba ti ọkọ ọhun n jona, naa jona.

O ni ṣugbọn oun dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ẹmi ẹnikẹni ko sọnu sinu ijamba ina naa.