Àwọn tọ́ọ̀gì ṣèkọlù sáwọn ọlọ́pàá níbi tí ìjàmbá ọkọ̀ ti wáyé

Oríṣun àwòrán, OGUN/POLICE
Kani kii ṣe ori to ko awọn ọlọpaa kan yọ lọwọ iku ojiji ni, o ṣee ṣe kí wọn ti dero ọrun alakeji nigba ti wọn l'awọn tọọgi koju ija si wọn lati lu wọn pa nibi ijamba ọkọ to waye laipẹ yii nipinlẹ Ogun.
Ọjọ Abamẹta tii ṣe Satide, ọsẹ to kọja la gbọ pe ijamba ọkọ ṣẹlẹ lagbegbe Orile-Imọ to wa nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, ipinlẹ naa.
Mọto meji ọtọọtọ ni iroyin fi to wa leti wi pe wọn kọlu ara wọn, nibi ti awọn eeyan ti farapa yannayanna.
Bi ijamba naa ṣe waye ni wọn l'awọn oṣiṣẹ alaabo oju opopona pẹlu awọn ọlọpaa to n dari ọkọ, ẹkun ti Owode Ẹgba ti sare debẹ lati ṣe iranwọ fawọn to farapa.
Awọn wọnyi la gbọ pe wọn ko awọn to farapa lọ si ile iwosan fun itọju to peye.
Lẹyin rẹ la gbọ pe awọn ọlọpaa lọ gbe mọto ti wọn fi n wọ ọkọ (tow vehicle), lati wọ awọn ọkọ naa lọ si teṣan wọn.
Nibi ti wọn l'awọn ọlọpaa ti fẹ wọ ọkan lara awọn ọkọ naa la gbọ pe awọn tọọgi ti ya bo wọn wi pe wọn ko gbọdọ wọ ọkọ kankan lọ teṣan wọn.
Loju ẹsẹ ni wọn sọ pe awọn ọlọpaa naa ti jẹ ko di mimọ pe o di dandan lati wọ awọn ọkọ ọhun lọ teṣan lati le ṣe iwadii kikun nipa ijamba, ti wọn l'awọn tọọgi naa sọ pe ko jọ ọ.
Igba ti wọn lawọn ọlọpaa fẹ fi tipatipa wọ ọkọ yii ni wọn l'awọn tọọgi yii fa awọn nnkan ija oloro yọ, ti wọn si bẹrẹ sii lu wọn.
"Nígbà tí àwọn tọ́ọ̀gì náà fẹ́ lu àwọn ọlọ́pàá náà pa ni wọ́n fẹsẹ̀ fẹ"
Bi iṣẹlẹ ọhun ṣe fẹẹ yiwọ, to si ti di pe niṣe ni wọn fẹẹ lu wọn pa, lo mu k'awọn ọlọpaa ba ẹsẹ wọn sọrọ, ti a si gbọ pe ọlọpaa kan, Sergeant Akinpẹlu Sunday farapa kọja sisọ.
Igba ti wọn de teṣan, ni wọn lọ royin ohun ti oju wọn ri, ti wọn si ni ọga wọn, iyẹn DPO Owode Ẹgba, CSP Ọlasunkanmi Popoọla lewaju awọn ọlọpaa rẹ lọ síbi iṣẹlẹ naa.
Wọn ni b'awọn tọọgi naa ṣe rii pe awọn ọlọpaa ko mu ọrọ naa ni kekere, lo jẹ ki wọn na papa bora, ṣugbọn ti ọwọ pada tẹ mẹta ninu wọn.
Awọn tọwọ tẹ naa ni Ọlayiwọla Baṣiru, Bamimore Isiaka ati Sọliu.
Agbẹnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi to gbe iroyin naa si BBC YORUBA leti lo jẹ ká mọ pe asiko ti awọn tọọgi naa fẹẹ dana sun mọto ọlọpaa ti wọn fẹẹ fi wọ ọkọ ni wọn debẹ.
Oyeyẹmi sọ pe wọn ti da bẹntiro si ara mọto naa, o si ku diẹ ki wọn ju ina si, l'awọn ọlọpaa sare debẹ.
O ni irinṣẹ kafinta bii 'Sledge Hammer, igi nla ati awọn nnkan ija oloro ni wọn fi koju awọn ọlọpaa, to si ni ori lo ko wọn yọ.
Siwaju sii lo fi ye wa pe owo to le diẹ ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta (₦520,000) naira ni awọn tọọgi naa ji ko ninu mọto awọn ọlọpaa lakoko ikọlu ọhun.
Ni bayii, ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki iwadii kikun bẹrẹ lori ikọlu ọhun, ati pe ọwọ gbọdọ tẹ awọn yooku to salọ, lati le foju winna ofin.















