Pósí oríṣí mẹ́ta ni Pope Benedict yóò sùn sí kí òkú rẹ̀ tó wọ ilẹ̀

Pope Francis n ṣe eto adura si oku Benedict XVI ninu gbọngan St Peter's Basilica

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Pope Francis n ṣe eto adura si oku Benedict XVI ninu gbọngan St Peter's Basilica

Eto isinku Pope Benedict XVI ti bẹrẹ ni gbagede St Peter Basilica.

Ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2022, lo ku ni ẹni ọdun marundinlọgọrun.

eyi waye lẹyin ọdun mẹwaa to kọwe fi ipo rẹ silẹ, nitori ilera ara rẹ.

Ṣaaju ni wọn ti tẹ oku rẹ si inu ile ijọsin St. Peter Basiclica ni Vatican fun ọjọ mẹta, nibi ti awọn eeyan ti ni anfaani lati ri fun igba ikẹhin.

Irọlẹ Ọjọru ni wọn ti ilẹkun ibẹ pa, ti wọn si pa posi ti oku Poopu nigba kan ri ọhun wa.

Botilẹ jẹ pe Pope Bendict beere fun ayẹyẹ isinku kekere, awọn eto kan to jọ ti Poopu to ṣi wa lori oye waye.

Lara iru eto bẹẹ ni lilo posi mẹta ṣaaju fun isinku rẹ.

Lẹyin ti wọn pari titẹ ni itẹ ẹyẹ, wọn gbe ara Pope Benecict sinu posi kan ti wọn fi igi atijọ siprẹsi ṣe. Wọn o si fi akọsilẹ nipa iṣẹ iranṣẹ rẹ gẹgẹ bi poopu sinu agolo kan, to fi mọ owo ẹyọ ti wọn ṣe lasiko idari rẹ, sinu posi naa.

Lẹyin naa ni wọn gbe e lọ si gbagede St Peter Square, nibi ti Pope Francis ti dari eto isin.

Lẹyin eto isin yii, wọn gbe oku Benedict XVI lọ si inu ile ijọsin St Peter Basilica, fun isin elero diẹ.

Nibẹ ni wọn o ti gbe sinu posi miran ti wọn fi irin ‘zinc’ ṣe, ko to o tun wọ inu posi onigi nla.

Awọn olukopa nibi isinku Benedict XVI

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Eero to kopa nibi eto isin idagbere ko pọ to ti Poopu to kọja, eyi ribẹ nitori pe Pope Benedict ti kuro nipo ko to o ku, ọpọ eeyan si ni ko gba tiẹ nitori ilana iṣakoso to lo
Pope Francis ni poopu akọkọ to sinku aṣaaju rẹ lẹyin ẹgbẹta ọdun

Oríṣun àwòrán, evn

Àkọlé àwòrán, Pope Francis ni poopu akọkọ to sinku aṣaaju rẹ lẹyin ẹgbẹta ọdun
Posi onigi 'Cypress' ni ikeji ti wọn gbe oku Benedict si ṣaaju isinku

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Posi onigi 'Cypress' ni ikeji ti wọn gbe oku Benedict si ṣaaju isinku
Apapọ awọn alufa agba 'Cardinal' ninu ijọ Katoliiki re e nibi isin idagbere naa

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Apapọ awọn alufa agba 'Cardinal' ninu ijọ Katoliiki re e nibi isin idagbere naa
Diẹ lara awọn to kopa nibi isin idagbere naa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Diẹ lara awọn to kopa nibi isin idagbere naa