Àwọn nǹkan ti yóò ṣẹlẹ̀ àti èyí tí kò níí wáyé níbi ètò ìsìnkú Pope Benedict XVI

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún eeyan ni ireti wa pe yoo ṣe ẹyẹ ikẹyin fun Poopu nigba kan rí, Pope Benedict XIV, nigba ti ayẹyẹ isinku ba bẹ̀rẹ̀.
Ọjọ aisun ọdun tuntun lo kú, lẹni ọdun marundinlọgọrun, lẹyin bi ọdún mẹwa to kọ̀wé fi ipo silẹ nitori ilera rẹ.
Pope Francis ni yoo dari eto isinku ni Ọjọbọ - oun ni yoo jẹ Poopu àkọ́kọ́ to sinku asiwaju rẹ.
Àwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì sọ pe eto isinku naa yoo lọ wọrọwọ lai si afẹfẹyeyẹ kankan.
Benedict XVI ni Poopu akọkọ to kọ̀wé fi ipo silẹ lẹyin ẹgbẹ̀ta ọdun ti iru rẹ waye kẹyin.
Ọjọ mẹta ni wọn o fi ṣi oku rẹ silẹ ninu posi ni ile ijọsin St Peter Basilica, fun awọn eeyan lati ma bu ọlá fun, titi di aago meje alẹ lojoojumọ.
Gbagede St Peter Square ni eto isin idagbere yoo ti waye, ki wọn to sin oku rẹ si ilẹ̀ isinku ni isalẹ Basilica.
Kaakiri agbaye ni àwọn eeyan ti n ṣe ìdárò iku Pope Benedict, ireti si wa pe ẹgbẹẹgbẹ̀rún eeyan ni yoo kopa nibi isinku rẹ.
Ọdun 2005 ni isinku Poopu waye kẹhun - isinku Pope John Paul II, wa lara awọn ipejọpọ Kristẹni to tobi julọ ni agbaye. Eeyan to to miliọnu mẹrin lo wa si Romu nitori rẹ.
Bi eto isinku Benedict yoo ṣe lọ ko tii daju, paapaa nitori pe awọn eto kan to rọ mọ isinku Poopu to wa lori oyè ko nii waye - paapa yiyan arọpo.

Oríṣun àwòrán, AFP












