Pope Benedict XVI jáde láyé lẹ́ni ọdun 95

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Olori nigba kan fun ijọ Katoliiki, Pope Benedict XVI ti jade laye lẹni ọdun marundinlọgọrun.
Iku rẹ waye lẹyin bi ọdun mẹwaa to finu-findọ fi ipo naa silẹ nitori ilera ara rẹ.
Pope Benedict dari ijọ Katoliiki fun bi ọdun mẹjọ, ko to o di pe o kọwe fi ipo silẹ.
eyi mu ko jẹ Poopu akọkọ to ṣe bẹẹ lẹyin Gregory XII lọdun 1415.
Ọgba awọn alufa Mater Ecclesiae to wa ni olu ile ijọ naa si lo gbe titi to fi ku.
Botilẹ jẹ pe ọjọ ti pẹ ti Poopu naa ti n ṣe aisan, awọn alaṣẹ ilu Holy see sọ pe aisan naa burẹkẹ si nitori ọjọ ori rẹ.
Joseph Ratzinger ni orukọ abisọ rẹ, ilu Germany ni wọn bi i si.
Poopu Benedict jẹ ẹni ọdun marundinlọgọrin nigba to de ipo lọdun 2005, to si jẹ Poopu to si wa lara awọn poopu to darugbo julọ to de ipo naa.
Oriṣiriṣi awọn awuyewuye ati ẹsun ni wọn fi kan ijọ Katoliiki lasiko iṣakoso rẹ - lara eyi ti wọn ti fi ẹsun biba ọmọde ni ibalopọ kan awọn alufa kan.
Ni ibẹrẹ ọdun yii, Poopu Bendict sọ pe lootọ ni awọn ṣe aṣiṣe nipa ọwọ ti wọn fi mu awọn ẹsun ibalopọ naa, lasiko ti fi jẹ biṣọọbu agba ilu Munich laarin ọdun 1977 si 1982.












