Gbogbo aburú tó bá fẹ́ ṣé ọmọ mi Isbae U, orí mi ni kó dà lé - Sir Kay sọ̀rọ̀ sílẹ̀

Sir Kay, àgbà òṣèré tíátà tó kú sọ̀rọ̀ sílẹ̀ fún ọmọ rẹ̀, Isbae U, láti fẹ̀mí ìmòore rẹ̀ hàn

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Gbajugbaja adẹrinposonu, Adabayo Ridwan, ti ọpọ mọ si Isbae-U ti sọrọ lori iku baba rẹ, Kamal Adebayo, gbajugbaja oṣere tiata, tí ọ̀pọ̀ eeyan mọ si Sir Kay to ku.

Ọjọ Kẹtadinlọgbọn osu Kejila ọdun 2022 ni Sir Kay jade laye lasiko aisan ranpẹ.

Ninu fọnran kan ti Isbae-U gbe soju opo ori ayelujara Instagram lati fi ṣe idaro baba rẹ, o ni oun ti padanu ololufẹ oun akọkọ.

O ni baba oun yii lo jẹ awokọse ti ko ni ẹlẹgbẹ fun oun, ti oun si ti di ọmọ orukan bayii.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Mó ti fúyẹ́, kò yé mi mọ́, ẹ̀rù ń bà mí lórí ikú Sir Kay, tíí ṣe bàbá mi - Isbae U

“Mo padanu Baba mi, ololufẹ mi akọkọ, ọrẹ mi. Mo ti fuyẹ, ko ye mi mọ, mo ti sọnu, N ko gba gbọ pe mo ti di ọmọ orukan bayi.

“Omije bọ loju mi, ẹru si n ba mi sugbọn gẹgẹ bii Musulumi ododo, wọn kọ wa lati maa dupẹ lọwọ Ọlọrun ni gbogbo igba.

Ọlọrun, iwọ lo tobi ju, mo dupẹ lọwọ rẹ, mo si gba ẹ gbọ nigbogbo igba.

Isbae-U tẹsiwaju pe oun gba ladura pe ki Ọlọrun fori jin baba rẹ, ko si pa gbogbo asise rẹ rẹ .

Sir Kay n gbadura fun Isbae U ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Isbae U/Instagram

Ki lo wa ninu fọnran ohun Sir Kay, ti Isbau U gbe sita?

Ninu fọnran ohun Sir Kay, to wa ninu fidio ibanikẹdun ti ọmọ rẹ, Isbae U gbe sita lo ti n se adura kikankikan fun alawada ori ayelujara naa.

Sir Kay ni ojoojumọ ni ọmọ oun maa n pọn oun le, dun oun ninu, to si n bu iyi kun oun ni awujọ awọn baba.

O ni bi Isbae U se n se aanu fawọn ẹbi rẹ, lo n se fun ara, ọrẹ ati ojulumọ, to si maa n mu ki inu oun dun nigba gbogbo.

O wa gba ladura pe Isbae U naa ko ni tẹ titi aye, gbogbo ohun to ba si dawọle, ni yoo maa yọri si rere.

"O n wọ asọ iyi fun mi, o jẹ ki gbogbo aye gbe mi ga, o n dun mi ninu, ọmọ yoo se iru rẹ fun iwọ naa.

Ridwan, o n ra ile aye gbe ree lati ara emi baba rẹ, awn ẹgbọn rẹ ati ẹbi, o ko ni jẹ egungun lẹyin ẹran."

"Ti mo ba si wa laye di ọdun to n bọ, mọto abi ile lo maa fun mi, bi Ọlọrun ba da ẹmi mi si"

Sir Kay tẹsiwaju pe "Gbogbo aye sa n la ẹnu silẹ ni pẹlu awọn ohun ribiribi to n se fun mi, o n ra ẹmi gigun fun mi pẹlu lojoojumọ.

Mo wa gbadura pe gbogbo aburu to yẹ ko se ẹ, ori mi ni ko da le.

Ti mo ba si wa laye di ọdun to n bọ, mọto abi ile lo maa fun mi, bi Ọlọrun ba da ẹmi mi si.

O n fun mi ni ẹnu ọrọ sọ, owo ko ni tan lapo rẹ, o ko ni mọ ebi lẹyin ayo.

Ọlọrun to ti sọ ẹ di olori, o ko ni di ero yin mọ, mo dupẹ pupọ, o seun o."

Bẹẹ ba gbagbe, Musiliu Akinsanya ti ọpọ mọ si MC Oluọmọ to jẹ eekan lara awọn ọrẹ oloogbe naa, lo kede iku gbajumọ oṣere naa loju opo Facebook rẹ lọsan ọjọ Iṣẹgun lẹyin ayẹyẹ ọdun Keresimesi.