Sir Kay wọ káà ilẹ̀ sùn lẹ́yìn oṣù mẹ́rin tí Isbae U ọmọ rẹ̀ fún ní ₦1m fún ọjọ́ ìbí

Sir Kay

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ń kọ ah! ah! lẹ́yìn tí ìròyìn ikú gbajúgbajà òṣèré nni, Kamal Adebayo tí ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ̀ sí Sir Kay kàn, bí pọ̀pọ̀ ṣìnṣìn ọdún Kérésìmesì ṣe ń tẹ̀síwájú.

Ọjọ́ Kẹtàdínlógún, oṣù Kejìlá ọdún 2022 sì ni àgbà òṣèré náà kí ayé pé ó dìgbóṣe.

Alága igbimọ to n se akoso ibudokọ ní ìpínlẹ̀ Eko, Alhaji Musiliu Akinsanya tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí MC Oluomo ló kọ́kọ́ kéde ikú Sir Kay ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun lórí ẹ̀rọ Facebook àti Instagram rẹ̀.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn gbajúmọ̀ òṣèré ló ti ń ṣe ìdárò ọ̀kan lára wọn tí wọ́n ṣe àfẹ́kù rẹ̀.

Ní báyìí òkú Sir Kay ti wọ káà ilẹ̀ sùn tí wọ́n sì ti sín ní ìlànà Mùsùlùmí.

Fídíò kan tó gba ẹ̀rọ ayélujára ṣàfihàn bí wọn ṣe sin òkú Sir Kay ní ìlànà Mùsùlùmí níbi tí ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ gbajúgbajà adẹ́rìnínpòṣónú, Isbae U báwọn péjú sí.

Àwọn Alfa, ará, ọ̀rẹ́, àwọn òṣèré tíátà lọ péjú síbi ètò ìsìnkú náà, tí ọmọbìnrin kan tí èròńgbà wà pé ó jẹ́ àbúrò Isbae U wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.

Fídíò náà ṣàfihàn Isbae U àti àwọn ènìyàn tó wà níbi ètò ìsìnkú náà tí wọ́n ń ṣe àdúrà ní ìlànà Mùsùlùmí fún òkú Sir Kay.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Owo ti Isbae U gbe fun baba rẹ

Oríṣun àwòrán, Isbae U/ Instagram

Osu mẹrin ni Isbae U, ọmọ Sir K fun baba rẹ ni owo beba miliọnu kan naira lọjọ ibi rẹ

Sir Kay gba owo beba ọgọrun kan miliọnu naira lọwọ Isbae U ọmọ rẹ lọsẹ diẹ sẹyin

Owo yii si ni ọmọ rẹ naa fi n mọ riri baba rẹ ni ayajọ ọjọ ibi rẹ.

Agba ọjẹ osere tiata naa, Sir Kay, ni baba adẹrinposonu kan lori ayelujara, Isbae U.

Isbae U ni iroyin rẹ gbalẹ́ ni ọsẹ diẹ sẹyin lori itakun agbaye pe o kọle ọlọgọrun kan miliọnu naira.

Losu kẹjọ ọdun 2022 si ni Sir Kay gba owo beba miliọnu kan naira lọwọ ọmọ rẹ naa.

Ọmọ rẹ ọhun, Isbae U lo kede ninu fidio kan lori ayelujara lori bo se gbe owo miliọọnu kan naa kalẹ fun baba rẹ.

Agba osere tiata naa si ni inu rẹ dun pupọ, to si n jo si orin ati ilu ti wọn n kọ.

Ohun ti Isbae U kọ soke fidio naa ni pe

“Mo fun baba mi ni owo beba miliọnu kan naira lati fi se ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ. Mo nifẹ rẹ, Baba mi (Sir K Kamor)

Ki Ọba oke tẹ oloogbe naa si afẹfẹ rere.