₦5bn lá à gbà lọ́wọ́ Sanwo-Olu, ìjọba àpapọ̀, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fún ẹbí Bolanle Raheem - NBA

Bolanle Raheem

Oríṣun àwòrán, Crostonshomes/Instagram

Ẹgbẹ awọn amofin nipinlẹ Eko NBA, ti beere fun biliọnu marun un naira gẹgẹ bi owo gba maa binu fun mọlẹbi amofin Omobolanle Raheem, ti ọlọpaa kan yinbọn pa lọjọ Keresimesi nipinlẹ Eko.

Ẹgbẹ awọn amofin naa ni oju awo lawo fi n gbọbẹ lawọn yoo ṣe pẹlu igbẹjọ ASP Drambi Vandi, ọlọpaa to sekupa Bolanle.

Amofin agba, Ẹbun Olu-Ọnagoruwa ṣalaye ninu atẹjade kan lọjọbọ pe oun gan ni ẹgbẹ NBA yan lati lewaju igbimọ oju awo lawo fi n gbọbẹ naa .

Oloogbe Raheem ati awọn ẹbí n pada sile ninu ọkọ wọn lagbegbe Ajah nilu Eko lọjọ Aiku Keresimesi ni, nigba ti ọlọpaa naa fi yin ni ibọn.

Sanwo-Olu, tete sanwo gba ma binu fun ẹbi Bolanle Raheem - Adegboruwa

Amofin Adegboruwa SAN sọ NI " Ẹka ẹgbẹ amofin Naijiria, NBA l’Eko pẹlu aarẹ apapọ ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Y.C. Mikyau, SAN ti pinnu lati darapọ mọ ikọ olupẹjọ fun ipẹjọ ọlọpaa naa.

Eyi wa gẹgẹ bi ara igbesẹ lati rii pe idajọ ododo ya kankan fun ẹbi oloogbe naa."

 Amofin Adegboruwa to ni oun ti ba agbẹjọro agba nipinlẹ Eko sọrọ, ni onitọun si ti fi da oun loju pe igbẹjọ yoo bẹrẹ ni kiakia.

Adegboruwa ni, “ ẹgbẹ Amofin Naijiria n beere fun owo gba maa binu fun mọlẹbi Bolanle Raheem lọwọ ijọba ipinlẹ Eko.

Bakan naa ni owo yii kan ijọba apapọ ati ileeṣẹ ọlọpaa pẹlu ajọ to n samuto isẹ ọlọpaa, PSC.

“Ẹgbẹ NBA yoo beere fun sisan owo itanran ti ko din ni biliọnu marun un naira pẹlu fifi ọlọpaa naa jofin.”

Bakan naa ni amofin Adegboruwa tun rọ gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu lati tẹle ilana to fi lelẹ lasiko igbimọ to gbe kalẹ lori ọrọ EndSARS.

"Sanwo-Olu yoo san owo gba maa binu fun ẹbi arábìnrin Raheem ni kiakia niwọn igba to jẹ pe a ti fi lọlẹ pe ọlopaa lo da ẹmi rẹ legbodo.”

Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá kò lágbára láti gba iṣẹ́ lọ́wọ́ òṣìṣẹ́ tó pa Bolanle Raheem - Agbẹnusọ ọlọ́pàá

Bolanle Raheem

Oríṣun àwòrán, Crostonhomes/Instagram

Ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Usman Alkali Baba ti palasẹ pe ki ọlọpaa ti wọn fẹsun kan pe o yinbọn lu agbẹjọro, Bolanle Rasheed ni agbegbe Ajah lọ maa rọọkun nile.

Drambi Vandi ni o wa ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ti Ajah, ti oun ati awọn ọlọpaa miiran si yinbọn lu Agbẹjọro ọhun pẹlu oyun ninu nigba ti oun ati mọlẹbi ti ile jọsin bọ lọjọ keresimesi.

Aikali ninu atẹjade ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejobi fi lede, o ni awọn gbe igbesẹ naa nibamu pẹlu ilana ofin to dirọ mọ ileeṣẹ ọlọpaa.

O tẹsiwaju pe igbesẹ ọhun yoo fi anfani silẹ fun ile ẹjọ lati gbe idajọ ododo kalẹ.

Ọga agba Akilali wa fi n da awọn ọmọ Najiriia loju pe oun yoo ri pe idajọ ododo jẹyọ.

O fikun pe saa toun gẹgẹ bii ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ko si ni fi aye silẹ fun iwa ọdaran ni awujọ papa julọ laarin awọn ọlọpaa ilẹ yii.

Alkali wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati ṣe suuru fun ileeṣẹ ọlọpaa lori isẹlẹ naa nitori awọn ti bẹrẹ iwadii, ti awọn yoo si kede si laipẹ yii.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ileesẹ ọlọpaa ko lagbara lati le ọlọpaa kankan lẹnu isẹ amọ asẹ pe ko lọ rọọkun nile la ni - Alikali

Wayi o, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nilẹ wa, Olumuyiwa Adejobi ti salaye pe ọga agba ọlọpaa kankan ko ni asẹ lati yọ osisẹ ọlọpaa kankan nisẹ.

Adejọbi fesi bẹẹ nigba to n dahun ibeere araalu kan to ni se lo yẹ ki wọn le osisẹ ọlọpaa to pa Bolanle Raheem lẹnu isẹ patapata ni.

Ninu alaye rẹ, Adejobi ni ajọ to wa fun akoso ileesẹ ọlọpaa lorilẹede yii, eyiun Police Service Commission (PSC) nikan lo ni agbara lati kede pe ki wọn le ọlọpaa kan lẹnu isẹ.

O fikun pe bi wọn se gba gbogbo agbara ati ẹtọ to ni gẹgẹ biii ọlọpaa, ti wọn si ni ko lọ rọọkun nile dabi ẹni pe wọn le lẹnu isẹ ni.

Adejobi wa fi ọwọ gbaya fawọn araalu pe ki wọn mase mikan, ko si giri nitori ọlọpaa naa yoo koju igbẹjọ to yẹ bayii.

"O di dandan ko foju wina ofin, ẹ ma mikan,asiko yii ni yoo koju igbẹjọ to yẹ bayii."

Ọrọ ti Olumuyiwa Adejobi sọ

Oríṣun àwòrán, Prince Olumuyiwa Adejobi

Àkọlé fídíò, Quest University Ghana: Ìyá àti ọmọ bọ́ sọ́wọ́ gbájúẹ̀ fásitì torí ìyanṣẹ́lódì ASUU

Mó kírì ọ̀sán kí n lè tọ́ ọmọ mi nílé ìwé, àmọ́ wọn kò jẹ́ kí n jẹun ọmọ - Màmá Bolanle

aworan

Oríṣun àwòrán, vanguard news/facebook

Iya Bolanle Raheem, agbẹjọro ti awọn ọlọpaa gbẹmi rẹ ni agbegbe Ajah nilu Eko ti salaye ohun ti oju rẹ ri, lasiko to n tọ awọn ọmọ rẹ.

Paapaa ko to di pe Bolanle Raheem kẹkọọ gboye lẹka imọ ofin, to si di agbẹjọro.

 Mama Bolanle sọ ọrọ yii nigbati Kọmisana ọlọpaa ipinlẹ Eko Abiodun Alabi ṣe abẹwo si idile ologbe naa. 

Bolanle Raheem

Oríṣun àwòrán, Bolanle Raheem/facebook

Ninu ọrọ iya ologbe Bolanle Raheem, o ni oun kiri ọsan, ṣe ọpọlọpọ iṣẹ lati ri wi pe ọmọ oun di agbẹjọro.

Sugbọn o ni o se ni laanu pe igba to yẹ ki ọmọ oun sanjọ ni awọn ọlọpaa ge ẹmi rẹ kuru.

Ninu aworan ti ile iṣẹ ọlọpa fi lede nipa abẹwo Komisona ọlọpa ti ipinlẹ Eko, ni ọrọ naa ti jad.

Awọn olubanikẹdun naa si n rọ iya ologbe naa lati fi ọrọ naa silẹ fun Ọlọrun lati ja fun.