Ẹgbẹ́ agbẹjọ́rò NBA fọnmú lórí bí ọlọ́pàá ṣe pa ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ l‘Eko

Sanwo-Olu lérí-lékà láti gba ìdájọ́ òdodo fún ẹbí amòfin tí ọlọ́pàá yìnbọn pa

Bolanle Raheem

Oríṣun àwòrán, Omobolanle Raheem

Ẹgbẹ Agbẹjọro nilẹ Naijiria, NBA, tí koro oju sì bí awọn ọlọpaa ṣe ṣekupa ọkan lara ọmọ ẹgbẹ wọn, Omobolanle Raheem lọjọ ọdun keresimesi ni agbegbe Ajah nilu Eko.

NBA ni kiakia, ki ileeṣẹ ọlọpaa kede orúkọ ọlọpaa to ṣe kọlu naa sita.

Iṣẹlẹ ọhun waye nigba ti oloogbe ati awọn mọlẹbi rẹ n ti ile jọsin bọ lọjọ Aiku to jẹ ọjọ keresimesi.

Ninu atẹjade to fi lede, Aarẹ NBA, Yakubu Chonoko ni ẹgbẹ naa n ṣe akitiyan lati ba awọn mọlẹbi ọhun kẹdun lori iku ọmọ ẹgbẹ.

O ni awọn si ti pinnu lati dìde iranlọwọ fun mọlẹbi ọhun.

Gbogbo ohun to yẹ ka mọ nipa isẹlẹ isekupani yii ni kileesẹ ọlọpaa Eko kede fun wa - NBA

Chonoko ni awọn ti bẹrẹ iwadi lori ọlọpaa to ṣe iṣẹ buruku ọhun, ti awọn si ti kan si Kọmisona fun Ileeṣẹ ọlọpaa fun ipinlẹ Eko, Abiodun Alabi.

O tẹsiwaju pe ileeṣẹ ọlọpaa ti fi idi rẹ mulẹ fun awọn pe orúkọ afurasi ọlọpaa to ṣekupa oloogbe naa ni ASP Drambi Vandi, ẹni to ti wa lẹnu isẹ ọlọpaa fun ọpọlọpọ ọdun.

"A rọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko lati kede orúkọ awọn ọlọpaa wọnyi fun gbogbo ọmọ Naijiria.

"Ẹ kede wọn fun wa, gbogbo nnkan to yẹ ka mọ ni kí ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko kede fun awọn ọmọ orile-ede Naijiria."

Sanwo-Olu bá àwọn mọ́lẹ̀bi kẹ́dùn, ó ní ìdájọ́ òdodo yóò wáyé 

Aworan Babajide Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Sanwo-Olu

Ijọba mi ko ni fi ọwọ lẹran lori iwa isekupani laibikitita - Sanwo-Olu

Bakan naa ni Gomina Ipinlẹ Eko, Gomina Babajide Sanwo-Olu ti ransẹ ibanikẹdun si mọlẹbi oloogbe Omobolanle Raheem.

Sanwo-Olu wa n fi da awọn mọlẹbi loju pe ijọba yoo ri pe idajọ òdodo waye lori isẹlẹ naa.

Sanwo-Olu ni o ṣe ni laanu pe awọn to yẹ ko da bobo awọn araalu naa lo tun ṣekupa wọn, sugbọn ijọba oun ko ni fi ọwọ lẹran lori ọrọ naa.

O ni inu oun dun pupọ pe afurasi apaniyan ti wa ni atimọle ileeṣẹ ọlọpaa, ti wọn si ti gba gbogbo ohun ija lọwọ re.

Gomina wa ro awọn eeyan ipinlẹ Eko lati ṣe suuru lori ọrọ naa atipe ìjọba ìpinlẹ Eko ti setan lati ri pe idajọ jẹyọ lori iku Omobolanle Raheem 

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Àkọlé fídíò, Engager in Amerika: Bukola Alphonso ní onílù kan ní kí òun lé tìróò láti rí owó gbà lágbo

Ọ̀gá Ọlọ́pàá pátá gbarata lórí ikú agbẹjọ́rò, ó lérí nípa ohun tí yóò ṣe fún afurasí ọlọ́pàá apànìyàn

Ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Usman Alkali Baba ti paṣẹ pe ki iwadii to ya kanmọ-kanmọ waye lori iku Amofin Ọmọbọlanle Raheem, ti ọlọpaa kan yinbọn pa.

Ọga ọlọpaa Alkali Baba tun paṣẹ pe ohunkohun ko gbọdọ di fifi kọlọransi ọlọpaa naa jofin ni kiakia.

O ṣalaye ninu atẹjade kan, eyi ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Ọmọọba Olumuyiwa Adejọbi fọwọsi, pe iṣẹlẹ buruku naa kii ṣe afihan ihuwasi ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria.

Ẹ̀yin ọlọpaa, ẹ maa fi iwa ọmọluabi kun isẹ yin - Ọga agba ọlọpaa

Bakan naa lo tun ba awọn ẹbi oloogbe naa kẹdun ẹni wọn to lọ.

O si tun kilọ fawọn ọlọpaa pe ki wọn maa fi iwa ọmọluabi kun iṣẹ wọn ni gbogbo igba.

Ọga agba ọlọpaa ni Naijiria naa tun fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe gbogbo ika to ba ṣẹ lori ọrọ naa ni ida ofin yoo ge.

Alaye ree lori bi ọlọpaa se yinbọn pa agbẹjọro lọjọ ọdun Keresimesi

Bolanle Raheem

Oríṣun àwòrán, @firstladyship

Ọlọpaa kan ti wọn ko darukọ rẹ ti yinbọn pa obinrin agbẹjọro kan, Bolanle Raheem, lagbegbe Ajah, nipinlẹ Eko.

Iroyin ni asiko ti oloogbe naa atawọn ẹbi rẹ n bọ lati ijọsin ọjọ ọdun Keresimesi ni iṣẹlẹ naa waye.

Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ, ọlọpaa ọhun atawọn akẹgbẹ rẹ gbiyanju lati mu ọkọ Bolanle duro ki iṣẹlẹ naa to waye.

Asiko ti ọkọ ti Bolanle wa ninu rẹ n gbiyanju lati yi obiripo to wa labẹ afara Ajah ni ọlọpaa naa ṣina ibọn bolẹ.

Amọ nigba ti wọn yoo fi gbe dele iwosan Bolanle ti jade laye.

Afurasi naa ti wa ni atimọle, iwadii ti bẹrẹ - Ọlọpaa

Ẹwẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hudeyin ti sọ pe iṣẹlẹ naa jẹ eyii to ṣeni laanu.

Ninu atẹjade kan loju opo Twitter rẹ, ọwọ awọn ti tẹ ọlọpaa to yinbọn pa oloogbe naa, yoo si foju wina ofin.

Hundeyin sọ pe “A ti fi ọlọpaa to yinbọn atawọn meji mii si atimọle.”

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

O fi kun pe awọn yoo tun tare ẹjọ naa lọ si ẹka ileeṣẹ ọhun to n ṣewadii iwa ọdaran ni Panti fun iwadii ni kikun.

Lẹyin naa lo ni ni kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Eko ti kan si awọn mọlẹbi oloogbe ọhun.

O ni “Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ba awọn ọrẹ ati mọlẹbi agbẹjoro Bolanle Raheem kẹdun.”

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

“Kọmiṣọna ọlọpaa, CP Abiodun Alabi ti kan si awọn ẹbi oloogbe naa ati ẹgbẹ awọn agbẹjọro, NBA lana, o si fi da wọn loju pe wọn yoo ri idajọ ododo gba.”

Wayi o, ọpọ awọn araalu lo ti bẹrẹ si n bu ẹnu atẹ lu ileesẹ ọlọpaa fun bi awọn oṣiṣẹ rẹ ṣe n dukoko, ti wọn si maa n fi iya jẹ araalu lọna ti ko ba ofin mu.