Ẹ má dìbò yan olóṣèlú tí yóò kọjú ìjà ṣii agbebọn - Gumi

Oríṣun àwòrán, others
Sheik Ahmad Gumi tii se gbajugbaja onimọ nipa ẹsin Islam lapa ariwa Naijiria ti ṣekilọ fawọn ọmọ Naijiria, papa julọ, awọn to wa ni ẹkun ariwa, lati mase dibo yan oloṣelu ti ko ni fori jin awọn agbebọn to ṣe kisa fawọn ara ariwa orilẹede yii.
Gẹgẹ Gumi ti sọ, awọn agbebọn ọhun jẹ jagunjagun ti ko yẹ ki ijọba orilẹ-ede yii pa, bikose lati bawọn ṣe ipade pọ.
Gumi lo sọ eyi di mimọ ninu iwaasu rẹ kan eyi to n ja ranin-ranin lori ẹrọ ayelujara twitter.
O wa rọ awọn eeyan ariwa orilẹede yii lati mase dibo yan ẹniti yoo kọju ija sawọn agbebọn to ba wọle gẹgẹ bi aarẹ.
Sugbọn Gumi ni ki wọn dibo yan ẹniti yoo bawọn joko jiroro, ti yoo si fun wọn ni ifẹ ọkan wọn.
Gumi jẹ ọkan ninu awọn ti awọn agbebọn maa n ri nigbati wọn ba fẹ gba owo itusilẹ tabi jiroro pẹlu ijọba.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Owo to yẹ kẹ fi kọle ẹkọ fawọn agbebọn, lẹ fi n ra ohun ijagun lati pa wọn - Gumi
Sheik Gumi si lo ti ṣepade pẹlu awọn afurasi agbebọn ni awọn igbo ni ipinlẹ Zamfara ati Kaduna.
O si tun ti rọ ijọba Naijiria ni ọpọlọpọ igba lati ṣe aforiji fun awọn agbebon gẹgẹ bo ti ṣe fawọn agbebọn lagbegbe Niger Delta.
Gumi ni ti ijọba apapọ ba ran awọn ologun si awọn agbebọn naa, eyi ko ni yanju ipenija aabo ti orilẹede yii doju kọ ṣugbọn yoo jẹ ki ipenija naa fẹju si ni.
Onimọ nipa ẹsin Islam naa fikun pe dipo bi ijọba apapọ ṣe n ra awọn eroja ijagun digboluja, se lo yẹ ko fi owo naa kọ ile iwe fawọn agbebọn naa .
Ọlọ́pàá mú àwọn afurasí tó jí Gbenga Owolabi tó nilé ìtura Tana Suites tí wọ́n pa lẹ́yìn tí wọ́n gba owó ìtúsílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Oyo Police
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Oyo ti fojú àwọn afurasí ajínigbé tí wọ́n fẹ̀sùn kàn wí pé àwọn ló wà nídìí jíjí ọmọ bíbí ìlú Ogbomoso kan tó ń gbé ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, Gbenga Owolabi gbé.
Ní inú oṣù kẹjọ ọdún 2022 ni àwọn ajínigbé jí Owolabi nígbà tó ṣe àbẹ̀wò sí ìlú abínibí rẹ̀.
Òun ló ni ilé ìtura tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tana Suites tó wà ní agbègbè Abaa ní Ogbomoso níbi tí àwọn ajínigbé náà ti ji gbé.
Owolabi àti akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ fásitì Ladoke Akintola University of Technology (LAUTECH), Ogbomoso Racheal Opadele tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìtura ni àwọn ajínigbé náà jí gbé pọ̀.
Àwọn ajínigbé náà ló ti kọ́kọ́ lọ sí ilé ìtura ọ̀hún ní ojú láti lọ bèèrè nípa ilé ìtura náà pẹ̀lú ìrètí wí pé wọ́n fẹ́ gba yàrá ní ilé ìtura náà.
Àmọ́ dípò kí wọ́n wá gba yàrá níṣe ni wọ́n padà sí ilé ìtura Tana Suite pẹ̀lú ìbọn àti àwọn nǹkan ìjà olóró láti jí ẹni tó ni ilé ìtura náà gbé lọ.
Lẹ́yìn tí àwọn ajínigbé náà ṣe iṣẹ́ ọwọ́ tán ni wọ́n bèèrè fún owó ìtúsílẹ̀ èyí tí àwọn ẹbí Owolabi kó kalẹ̀.
Káká kí àwọn ajínigbé náà tú Owolabi àti Racheal sílẹ̀ wọ́n ṣekúpa àwọn méjéèjì ni kódà wọ́n sì tún pa ọlọ́kadà tó gbé ẹni tó gbé owó ìtúsílẹ̀ náà lọ fún wọn.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti wá kéde pé ọwọ́ ti tẹ àwọn afurasí ajínigbé náà.
Báwo ni ọwọ́ ṣe tẹ̀ wọ́n?
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Oyo, Adebowale Williams ní ọjọ́bọ̀ tó ń ṣàfihàn àwọn afurasí náà ní oríkò iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tó wà ní Eleyele, Ibadan ní ẹnìkan tó ti kó sọ́wọ́ àwọn afurasí náà rí ló ṣe àtìléyìn bí àwọn ṣe rí wọn mú.
Williams ní ìwádìí ṣì ń lọ lọ́wọ́ àti pé ní kété tí àwọn bá ti parí ni àwọn máa gbé àwọn afurasí lọ sí ilé ẹjọ́.















