Ọba Charles gbarata lórí ọ̀wọ́n oúnjẹ àti ebi tó gbòde lásìkò ọdún Keresimesi

Kings Charles III

Ọba ilẹ Gẹẹsi, Ọba Charles Kẹta ti fi ọrọ ikinni ọdun Keresimesi akọkọ lede gẹgẹ bii ọba ilẹ naa.

Ninu ọrọ ikini naa lo ti mẹnuba bi nnkan ṣe wọn gogo nilẹ ọhun ati lagbaye.

O ni oun mọ pe ọpọ awọn araalu ni ko rọrun fun lati tọju awọn ẹbi wọn lasiko yii.

Ninu ọrọ ọdun naa to sọ nile ijọsin St George’s Chapel to wa nile nla Windsor Castle, ni Ọba Charles Kẹta ti gboriyin fun iya rẹ fun awọn ohun to gbe ṣe lasiko to wa loke eepẹ.

"Mo dupẹ lọwọ awọn oninure to fun awọn eeyann lounjẹ lasiko ọdun yii"

Ọba Charles Kẹta ni “Mo fẹ dupẹ lọwọ awọn oninu ire to fun awọn eeyann lounjẹ atawọn ẹbun mii lasiko ọdun yii.”

O tun sọrọ ifẹ ti awọn ọmọlẹyin Kristi fi n han si awọn ẹlomiran lasiko pọpọ-ṣinṣin ọdun.

Ọba Charles Kẹta ni “Mo dupẹ lọwọ ẹyin araalu fun ifẹ ti ẹ fi han si emi atawọn ẹbi mi.”

“Akoko ọdun Keresimesi ṣe pataki si awa to ti padanu awọn ololufẹ tabi ẹbi wa, gbogbo igba ti ọdun naa ba n waye ni a maa n saaro wọn.”

Àkọlé fídíò, Engager in Amerika: Bukola Alphonso ní onílù kan ní kí òun lé tìróò láti rí owó gbà lágbo

"Ẹ maṣe sọ ireti nu tori awọn iṣẹlẹ to n waye kaakiri agbaye"

O tun dupẹ awọn ọmọ ogun fun bi wọn ṣe n daabo bo araalu, to fi mọ awọn oṣiṣẹ pajawiri, oṣiṣẹ eto ilera atawọn olukọ.

Lẹyin naa lo gba awọn araalu niyanju lati maṣe sọ ireti nu nitori oniruru awọn ohun to n ṣẹlẹ kaakiri agbaye.

Ọdọọdun ni ọba ilẹ Gẹẹsi maa n fi ọrọ ikinni ranṣe si awọn eeyan rẹ, wọn ti n ṣe bẹẹ bayii o ti le ni aadọrun ọdun.