Alága ìdúró mú ohùn mi lọ lójú agbo tí mo tí ṣe alága ìjókòó l‘Amẹ́ríkà - Bukola Alphonso-Olanrewaju

Àkọlé fídíò, Engager in Amerika: Bukola Alphonso ní onílù kan ní kí òun lé tìróò láti rí owó gbà lágbo
Alága ìdúró mú ohùn mi lọ lójú agbo tí mo tí ṣe alága ìjókòó l‘Amẹ́ríkà - Bukola Alphonso-Olanrewaju

Engager in Amerika: Bukola Alphonso-Olanrewaju ní onílù kan ní kí òun lé tìróò láti rí owó gbà lágbo

Ko si isẹ kankan ti ko ni ipenija nitori ẹni ti yoo ga, ẹsẹ rẹ yoo tiirin.

Bẹẹ ni ọrọ ri fun obinrin kan to n fi isẹ alaga iduro ati ijokoo sisẹ se ni Amẹrika, Bukola Alphonso-Olanrewaju, ti oju rẹ ti ri ọpọ ipenija nidi isẹ naa loke okun.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ Bukola Olanrewaju lori ohun to mu ko yan isẹ naa laayo, o ni ọwọ iya oun ni oun ti jogun isẹ naa, ti oun si nifẹ si pupọ.

O fikun pe gbajumọ agbohunsafẹfẹ ni oun lorilẹede Naijiria, ki oun to yan isẹ alaga iduro laayo ni Amẹrika, ti oun si n se bẹbẹ nidi isẹ naa.

Bakan naa lo n dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o n fi isẹ naa rọ oun lrun bi o tilẹ jẹ pe oun n ri awọn ipenija nla lẹnu isẹ naa bi oun se wa loke okun.

Bukola atawọn oyinbo to n se igbeyawo

Oríṣun àwòrán, auntybcompereevents/Instagram

"Tori n ko se ẹgbẹ alaga iduro ni Amẹrika, wọn mu ohun mi lọ loju agbo"

Nigba to n mẹnugba ipenija kan gbogi to ba finra nidi isẹ alaga iduro, Arabinrin Bukola Alphonso-Olanrewaju ni wọn ti mu ohun oun l ri loju agbo.

"Mo lọ sibi idana kan bii alaga ijoko ni Amẹrika, mo si pade obinrin kan to jẹ alaga iduro pade nibẹ.

O bi mi pe se mo wa ninu ẹgbẹ, mo si ni rara, n ko nilo lati se ẹgbẹ kankan ki n to siẹ mi bii alaga ijokoo, lo ba dakẹ.

Amọ nigba ti ayẹyẹ idana naa bẹrẹ, se ni ohun mi lọ fee, ti n ko si ri ohun naa lo, titi ti ayẹyẹ naa fi pari."

Bukola ni lẹyin ayẹyẹ ọhun ni alaga iduro naa wa ba ohun pe se oun ti ri bayii, oun sa ni oun ko ni se ẹgbẹ?

O ni oun ko tilẹ fun ni esi kankan ju pe ohun fa le Ọlọrun lọwọ lọ, ti oun si kuro loju agbo naa.

Bukola ati awọn onilu ni Amẹrika

Oríṣun àwòrán, auntybcompereevents/Instagram

"Onilu kan ni isẹ mi dara amọ o yẹ ki n tẹ ẹ nidii, ki n le maa ri owo pa loju agbo"

Bakan naa ni Bukola Alphonso-Olanrewaju sọ nipa ọna kayeefi tawọn alaga iduro, alaga ijokoo atawọn onilu wọn maa n gba pa owo loju agbo.

O ni ni Amẹrika ni ohun ti gbọ pe kii se oju lasan ni awọn alaga ati onilu kan n lo lati pa owo wọle nitori pe wọn maa n lo oogun abẹnu gọngọ lati pawo lode inawo.

"Nibi ayẹyẹ kan, mo lo onilu kan lọjọ naa ta si se daadaa amọ ẹyin idana naa lo wa ba mi pe isẹ mi dara amọ mo nilo lati tẹ ẹ nidi.

O ni ti mo ba tẹ isẹ mi nidii, awọn alejo to wa sibi inawo naa yoo maa nawo fun mi titi ti wọn yoo fi ya owo ọkọ lọ sile.

Bakan naa lo tun sọ fun mi pe ọpọ onilu atawọn alaga iduro lo maa n le tiroo, ẹni to ba si le tiroo nikan ni yoo maa ri owo pa loju agbo."

Bukola ni lati ọjọ naa ni onilu ọhun ti ba oun sisẹ kẹyin nitori ohun ti Ọlọrun ba pe ni ọna eeyan, yoo fi rọ eeyan lọrun ni.

Bukola ati awọn to n dana

Oríṣun àwòrán, auntybcompereevents/Instagram

"Oju agbo ni imisi orin ti maa kọ ti maa n wa, bi mo se n kọ orin oyinbo, ni mo n kọ ti Yoruba"

Bukola Alphonso-Olanrewaju fikun pe Ọba Oke fi isẹ alaga iduro naa rọ oun lọrun nitori oju agbo ni imisi orin ti oun yoo kọ, ti maa n wa.

O ni o rọrun fun oun lati kọ orin tabi sọ ede oyinbo, ti oun yoo si tun tumọ rẹ ni ede Yoruba ati nida keji bakan naa.

O ni irọrun ti de ba isẹ alaga iduro lasiko yii nitori ọpọ awo orin ifẹ lo ti wa nita, ti awọn si maa n ha sori lati fi dara loju agbo pẹlu awọn ajasa to lagbara.

Bukola salaye pe oun kii gba akoko awọn alejo rara nitori pe owo to ba tẹ oun lọrun ni oun maa n gba gẹgẹ bii owo isẹ lọwọ awọn oninawo.

"Emi kii lo ju wakati kan lọ fun idana, mo si maa n sọ fun awọn alejo pe mo ti gba owo isẹ mi pe lọwọ oninawo, to ba wu awọn alejo ni ki wọn nawo fun mi."

Nigba to n sọrọ lori bawọn ọkunrin naa se n sisẹ alaga iduro, Bukola ni ko si ohun to buru ninu rẹ nitori tawọn ọkunrin yii gan ga pupọ.