Buhari, àlùfáà rẹ ń sanra, ìjọ ń rù, ṣé bí ìlera rẹ ṣe rí lọ́dún 2015 tó o dépò rèé? – Kukah

Oríṣun àwòrán, @MBuhari
Ipo ti Buhari fẹ fi awọn ọmọ Naijiria silẹ si buru ju bo se ba wọn lọ - Kukah
"Buhari, bo o ṣe ba wa lọdun 2015 kọ lo ṣe fẹ fi wa silẹ lọdun 2023" ni ọrọ ti Biṣọbu agba ijọ katoliki ni Sokoto, Matthew Hassan-Kukah fi bọnu ninu ọrọ ikini ku ọdun Keresimesi to sọ lọjọ Aiku.
Biṣọbu Kukah ni pẹlu gbogbo ileri sọgbẹdigboro ti Buhari ṣe fun awọn ọmọ Naijiria ki o to wọle sipo aarẹ lọdun 2015, ipo to n fi ọmọ Naijiria silẹ si “buru pupọ pupọ” ju ipo ti wọn wa nigba to de ipo lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2015.
"Bawo ni ko ba ti dunto kawọn ọmọ Naijiria naa ni anfaani si eto ilera ti Buhari jẹ igbadun rẹ"
Biṣọbu ijọ Aguda naa ṣalaye wipe alufa n sanra ijọ n ru ni Aarẹ Muhammadu Buhari n fọrọ Naijiria ṣe.
O ni ko si aniani pe ipo ilera aarẹ bayii ti yatọ gidigidi si bo ṣe wa ni igba to fẹ wọ ipo aarẹ lọdun meje abọ sẹyin.
Kukah fikun pe to si jẹ pe ipo ti eto ilera wa fun mẹkunu ni Naijiria ko ṣe maa fi ẹnu sọ.
O ni bawo ni ko ba ti dara to ko jẹ pe awọn ẹgbẹlẹgbẹ ọmọ Naijiria ti aarẹ jẹ olori le lori, lee lanfani si iwọnba ida perete eto ilera ti aarẹ n janfani rẹ.

Oríṣun àwòrán, The Kukkah Center
Hassan-Kukah kan sara si Buhari lori ipese ohun amayedẹrun ati afọmọ eto idibo
“Aarẹ, mo ki yin ku ọdun keresimesi lorukọ ara mi ati gbogbo ọmọ Naijiria.
A dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ilera yin.
A mọ pe afẹfẹ ilera to n fẹ si yin bayii pọ ju ti tẹlẹ lọ nitori pe o han ninu bi ẹ ṣe n gbe ẹsẹ ati ẹgbẹlẹgbẹ maili irinajo ti ẹ n rin lọ si oke okun.
“Amọ ṣa, ko ba dara ka ni ẹgbẹlẹgbẹ ọmọ Naijiria pẹlu le e lanfani si iwọnba perete ninu odiwọn eto ilera ti ẹ n janfani rẹ, nipa ipese eto ilera to kun oju owo lorilẹede wa.
Biṣọbu Hassan-Kukah wa kan sara si aarẹ lori awọn igbesẹ to loorin to gbe lẹka ipese ohun amayedẹrun ati ṣiṣe afọmọ eto idibo lorilẹede Naijiria.
Bakan naa lo tun gba adura fun eto idibo alaafia ti ko ni lẹjanbakan ninu lọdun 2023 lorilẹede Naijiria.















