Ìdí rèé tí ọkàn mi ṣe balẹ̀ pé ọkọ mi kò le fẹ́ ìyàwó míràn - Toyin Abraham
Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ni mo gbọ̀ nípa ọkọ mi àmọ́ mo mọ̀ pé kò ní àlè síta - Toyin Abraham

Oríṣun àwòrán, Toyin Abraham/facebook
Gbajugbaja oṣere tiata, Toyin Abraham, ti ṣalaye pe igbeyawo oun pẹlu Kolawole Ajeyemi n lọ geere nitori ifọwọsowọpọ ati igbọraẹniye to wa laarin awọn. Toyin Abraham, ẹni to woye bẹẹ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to se tun ni ko si iwe atọnisọna fun igbeyawo nitori iwa onikaluku yatọ si ara wọn.
O ni awọn ọkunrin miran le maa le sọ ọrọ ẹnu wọn tan, ti awọn miran ko si ri bẹ. Toyin ni laarin oun ati ololufẹ oun Kolawole Ajeyemi, awọn ko jọ ni asunwọn ifowopamọ kan naa. O ni ọpọlọpọ igba ni awọn dijọ ṣe itọju ile nitori wi pe ti oun ko ba si nile, ọkọ oun Kolawole ni yoo ṣe gbogbo inawo inu ile, bẹẹ gẹgẹ ni oun naa maa n ṣe. Mama Ire ni ọpọlọpọ igba ni awọn dijọ kowojọ papọ ṣe akanṣe iṣẹ nitori ati oun ati Kolawole, ni awọn mọ iye to wa ninu apo asunwọn owo ẹnikọọkan awọn nile ifowopamọ ẹnikọọkan.
"Kolawole n fi inu kan ba mi se"
Toyin ninu ifọrọwerọ naa ni igbeyawo dabi ile iwe ti ko ni ọjọ ti a maa kawe gboye tan nitori gbogbo igba ni oun gbiyanju lati ri wi pe igbeyawo naa ko tuka. Bo tile jẹ wi pe ọpọlọpọ ọrọ ni oun ti gbọ nipa ọkọ oun, amọ ifẹ rẹ si duro digbi lookan aya oun ni nitori wi pe Kolawole n fi inu kan ba oun ṣe. Toyin ni igbẹkẹle ti oun ni ninu ọkọ oun lo jẹ ki ọkan oun balẹ pe Kolawole ko ni aale nita tabi ko ni ọrẹbinrin sita.
O ni ọkọ oun ko si le fẹ iyawo miran lẹyin oun bo tilẹ jẹ wi pe kọ rọrun sugbọn igbagbọ oun ni wi pe Kolawole ṣe fi inu tan.

Oríṣun àwòrán, Toyin Abraham/Facebook
''N ko fẹ ki iwọsi kankan ta ba Kolawole ni mo se maa n gbọran si lẹnu ni gbogbo igba''
Toyin Abraham ni ifẹ yii lo jẹ ki oun ati ọmọdebinrin ti ọkọ oun kọkọ bi lati ipasẹ obinrin miran fẹran ara awọn, ti oun si mu gẹgẹ bi ọmọ bibi oun. Toyin Abraham ni ọpọlọpọ igba ni awọn jọ ma n ṣe iṣẹ papọ gẹgẹ bi oṣere tiata sugbọn ọpọlọpọ igba ni awọn ko jẹ ki isẹ tiata ba ifẹ to wa laarin awọn jẹ.
Toyin ni oun ko fẹran ki iwọsi ta ba Kolawole ọkọ oun, nitori naa ni oun ṣe ma n gbọran si lẹnu ni gbogbo igba.











