Wo àrà méèrírí mẹ́wàá tí o kò mọ̀ nípa Keresimesi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdọdun lawọn ọmọlẹyin Kristi kaakiri agbaye maa ṣajọyọ ọdun Keresimesi.
Ọjọ naa lawọn Kristẹni fi maa n ṣeranti ọjọ ibi Jesu Kristi.
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn onimọ lo ti sọ pe kii ṣe ayajọ ọjọ ọhun ni wọn bi Jesu amọ gbogbo awọn Kritẹni ti gba ọjọ naa gẹgẹ bii ọjọ ibi rẹ.
Ni ayajọ ọjọ Keresimesi, ayẹyẹ nla lo maa n waye, ti awẹjẹ-wẹnu yoo si wa, ti inu awọn ọmọlẹyin Kristi yoo si maa dun pe ọdun naa ba awọn nile aye.
Amọ bi ọdun Keresimesi ti se pataki to yii, awọn ohun ara pataki kan wa, ti ẹ ko mọ nipa ọdun naa.
Awọn ohun mẹwaa to ṣeeṣe ki o ma mọ tẹlẹ nipa ọdun Keresimesi
Idaji awọn eeyan to ni ẹranko gẹgẹ bii ohun ọsin ninu ile nilẹ Amẹrika lo maa n ra ẹbun ọdun fun awọn ẹranko wọn lasiko ọdun Keresimesi.
Iye owo ẹbun kọọkan si maa n to dọla mẹrindinlaadọta, eyiun $46.
Ilu kan wa lorilẹ-ede India ti orukọ rẹ n jẹ Santa Claus.
Gẹgẹ bii iwadii St. Nick, Santa (iyẹn baba Keresimesi) ko sanra rara.
Bẹẹ ni aṣọ pupa ati irugbọn rẹ funfun ti awọn eeyan mọ mọ Baba Keresi lonii jẹ eyii ti wọn fi n polowo ọja fun ileeṣẹ ẹlẹrindodo Coca-Cola.
Iwadii ni ọsẹ diẹ ṣaaju ọjọ Keresimesi gan ni ọpọ lọkọ-laya maa n tuka.
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo gbagbọ pe awọn amoye mẹta kan fun Jesu ni ẹbun lọjọ ibi rẹ, bibeli ko sọ iye awọn amoye naa, iwe Matthew sọ pe “awọn amoye.”
Onkọtan ọmọ ilẹ Amẹrika, Washignton Irving lo ya awọran “Santa’s sleigh” to jẹ ti baba Keresi to wa lori kẹkẹ ẹlẹṣin.
Ọpọ eeyan lo maa n mu ọti yo lasiko ọdun Keresi ti wọn ba n ṣajọyọ, amọ ọpọ awọn ojiṣẹ Ọlọrun lo ti bu ẹnu atẹ lu iwa naa.
Bibeli ko darukọ ọjọ pato ti wọn bi Jesu, amọ ọpọ awọn onkọtan gbagbọ pe akoko otutu ni.
To ba jẹ pe lootọ ni Santa n wa lati South Pole lati pin ẹbun fun awọn eeyan, o n tumọ si pe yoo sare ju afẹfẹ lọ, yoo si maa ya ile 800 laarin iṣẹju aaya kan.
Awọn arinrinajo kan ti wọn pe ni "puritan pilgrims" kọ lati ṣe ayẹyẹ ọdun Keresi laarin ọdun 1659 si 1682.
Bẹẹ si ni ẹṣẹ nla ni labẹ ofin lọdun naa lọhun, ki eeyan kan kọ lati mase se ajọyọ ọdun Keresimesi.












