Gómìnà Makinde buwọ́lu ìṣúnà N310.4bn fún ìpílẹ̀ Oyo f’ọ́dún 2023 nílùú Saki

Oríṣun àwòrán, oyo state government
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde ti buwọlu eto iṣuna tuntun fun ipinlẹ Ọyọ lọdun 2023.
Makinde buwọlu abadofin naa eyi to fun ni akori, “iṣuna idagbasoke to yanranti” ni ilu Ṣaki lẹkun Oke Ogun ni ipinlẹ naa.
Igba akọkọ niyi ti gomina ipinlẹ naa yoo maa buwọlu abadofin iṣuna ipinlẹ naa ni ibi ti kii ṣe ọfiisi gomina ipinlẹ Ọyọ.
Gomina Makinde to kan sara si awọn aṣofin ipinlẹ naa fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe lati rii pe aba iṣuna ipinlẹ naa jade ṣaaju wiwọnu ọdun 2023 ṣalaye pe bibuwọlu abadofin ọhun yoo mu ki igbesẹ ati pari awọn akanṣe iṣẹ waye ni kiakia fun idagbasoke ipinlẹ Ọyọ.
Makinde ni iṣejọba oun ni ṣiṣẹ lati rii pe owo apawọle labẹle (IGR) fun ijọba Ọyọ gbẹnu soke sii kọja biliọnu mẹta o le ẹgbẹrin miliọnu, (N3.8 billion).
“Mo ti buwọlu ofin eto iṣun ni ilu Ṣaki ti a wa bayii. Akọsilẹ rere ni eyi”

Oríṣun àwòrán, Oyo state government
Awọn gomina miran to ti buwọlu abadofin iṣuna wọn fun ọdun 2023
Yatọ si gomina Makinde awọn gomina miran to ti buwọlu abadofin ọdun 2023 bayii niwọn:
Gomina Bala Mohammed ti ipinlẹ Bauchi buwọlu abadofin ti owo rẹ le ni biliọnu mejilelugba o le ẹgbẹta miliọnu, (N202.6bn)

Oríṣun àwòrán, twitter/arakunrin akeredolu
Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu buwọlu abdaodin ipinlẹ naa fun ọdun 2023 nilu Akurẹ.
Abadofin ipinlẹ Ondo to le ni biliọnu mẹtalelaadọsan naira naa lo pe akori rẹ ni eto “iṣuna ajọni ọla”
Gomina Muhammad Badaru ti ipinlẹ Jigawa pẹlu ti buwọlu abadofin ipinlẹ naa fun ọdun 2023.
Akojọpọ iṣuna naa jẹ biliọnu mejilelaadọsan.
O ṣalaye pe abadofin ọdun 2023 yoo tubọ tẹsiwaju lori awọn aṣeyọri to ti waye laarin ọdun meji sẹyin.












