UK Travel list: Nigeria wà lára àwọn orílẹ̀-ède tí UK ṣe àfikún sí òfin tó de àwọn eèyàn wọn tó fẹ́ wá sí Naijiria láti UK báyìí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orílẹ̀-ède UK ti gbégi lé àwọn arìnrìàjò láti Nàìjíríà nítorí…
Orukọ orilẹ-ede Naijiria wa lara awọn ọgọsan orilẹ-ede ti ilẹ Gẹẹsi gbe ami ikilọ le fawọn eeyan rẹ.
Eyi fihan pe ẹnikẹni ti n gbe nilẹ Gẹẹsi ko ni lee rinrinajo wa si Naijiria tabi eyikeyi awọn orilẹ-ede ti wọn darukọ naa yala lati wa gbafẹ ni tabi fun isinmi.
Bakan naa lo tun ni nnkan ti awọn eeyan lati orile-ede wọnyi gbọdọ ṣe fun ọjọ mewaa saaju rinrinajo wa si ilẹ Gẹẹsi.
Igbesẹ yii n waye pẹlu bi awọn alaṣẹ orilẹede Gẹẹsi ṣe pinnu lati ṣi awọn papakọ ofurufu rẹ silẹ fun Irinajo silẹ okeere.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ilẹ Gẹẹsi ni eyi lee bẹrẹ diẹdiẹ ni ọjọ kẹtadinlogun, osu karun un, ọdun 2021.
Ikede naa fihan pe awọn eeyan orilẹ-ede naa lee rinrinajo lọ silẹ okeere fun afẹ lai tapa si ofin.
Awọn orilẹede mejila ni wọn wa labi ipele kosifoya ninu àkọsílẹ ijọba ilẹ Gẹẹsi naa.
Eyi tumọ si pe awọn eeyan to ba rinrinajo wa sorilẹede Gẹẹsi latawọn orilẹede bẹẹ ko ni nilo ki wọn fi wọn sabẹ igbele bẹrẹ lati ọjọ kẹtadinlogun osu karun un.
Ipele to fẹ ju ni ipele ewu n bẹ loko longẹ ti orukọ orilẹ-ede Naijiria bọ si pẹl'awọnorilẹde miran lati ilẹ Yuroopu bii Spain, Italy ati France.

Awọn to ba rinrinajo wa si ilẹ Gẹẹsi latawọn orilẹede naa yoo koko wa ni yara igbele fun bi ọjọ marun un gbako.
Ṣugbọn alakoso eto irinna nilẹ Gẹẹsi, Ọgbẹni Grant Shapps ṣalaye pe ki awọn olugbe orilẹede Gẹẹsi o yẹra fun rinrinajo lọ sawọn orilẹ-ede naa.
- Mi ò bú Baba Adeboye, mo kàn gégùn-ún fún àwọn tí kò ṣàtìlẹyìn fún Oduduwa Republic ni- Sunday Igboho
- Ìjọ Kátólìkì, ẹ jèbùrẹ́, ọmọdé ló ṣe èmi àtàwọn ọmọ ìjọ mi- Father Mbaka
- Wo orísun agbára tí Sunday Igboho gbójúlé tí ọwọ́ ẹnikẹ́ni kò fi le tẹ̀ ẹ́
- Emmanuel Abina, ọmọ Olùdarí ìjọ GOFAMINT, Elijah Abina jáde láyé lẹ́yìn ikú ìyàwó rẹ̀
Wo awọn ohun ti o ni latiṣe ki o to lee rinrinajo lọ si ilẹ Gẹẹsi bayii:
1.O gbọdọ buwọlu fọọmu ibugbe arinrinajo ti wọn pe ni "passengers locator form"
2.O gbọdọ ti se ẹwo arun COVID-19.
3.O gbọdọ ti forukọsilẹ fun ayẹwo kokoro arun COVID-19 ọlọjọ keji ati ọlọjọ kẹjọ.
4.Bi o ba de orilẹde Geesi gbara, o wa ni ivbeke fun ọjọ mẹwaa.
5.O gbọdọ ṣe ayẹwo ti o ti forukọsilẹ fun ni ọjọ keji ati ikejọ ti o ba gunlẹ silẹ Gẹẹsi.
Awọn orilẹ-ede ti awọn ọmọ ilẹ Gẹẹsi lee rinrinajo lọ ti wọn ko ni fi wọn si igbele biwọn ba de:
Portugal
Israel
Singapore
Australia
New Zealand
Brunei

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iceland
Gibraltar
Falkland Islands
Faroe Islands
South Georgia and the South Sandwich Islands.
St Helena, Tristan de Cunha, Ascension Island.














