Emmanuel Folorunso Abina, ọmọ Olùdarí ìjọ GOFAMINT, Elijah Abina jáde láyé lẹ́yìn ikú ìyàwó rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Instagram/gofamint
Pasitọ Elijah Abina, to jẹ adari ijọ Gospel Faith Mission International, GOFAMINT, ti padanu ọmọ rẹ ọkunrin, Emmanuel Folorunso.
Iroyin iku ọmọ Pasitọ Abina jade lẹyin ọjọ diẹ ti ọmọkunrin Pasitọ agba ijọ Redeem, Enoch Adeboye naa jade laye.
Iroyin sọ pe ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2021, ni Emmanuel Abina ku nilu Eko.
Eyi to jẹ ọjọ kẹjọ ṣaaju iku ọmọ Adeboye.
- Mi ó ṣọ̀fọ̀, mo sọkún nítorípé... - Ìyàwó olóògbé Dare Adeboye sọ̀rọ̀ níbi ìsìn idágbére ọkọ rẹ̀
- A kò ní pe Ọlọ́run ní ẹjọ́ lórí ìkú ọmọ wa, Dare Adeboye - Ẹbí Adeboye
- Ìyàwó Adeboye gbàdúrà fún Nàìjíríà ní ìgbà akọkọ tó fara hàn lẹ́yìn ikú ọmọ wọn, Dare
- Ẹbí Adeboye kéde bí ìlànà ikú Pásítọ Dare yoo ṣe lọ
- Ìjọba Ààrẹ Buhari ti kùnà, kò le è sí ìfìmọ̀ṣọ́kan lábẹ́ ìṣèjọba rẹ̀ ní Naijiria- Wole Soyinka
- Wo orísun agbára tí Sunday Igboho gbójúlé tí ọwọ́ ẹnikẹ́ni kò fi le tẹ̀ ẹ́
- Báwo ni ìṣẹ̀lẹ̀ ikú Kayode Badru ṣe ṣẹlẹ̀ ní Celestial Church of Christ ni Eko? ẹ wo ohun tí a mọ̀!
Bo tilẹ jẹ pe a ko ti i le sọ pato nkan to pa Emmanuel, iroyin sọ pe aisan ọlọjọ diẹ lo pa a.
Ṣaaju iku rẹ, oun ni pasitọ ẹka ijọ GOFAMINT, Kingdom House Assembly to wa ni Festac Town nilu Eko.
Bakan naa lo tun jẹ oludari ẹka igbohunsafẹfẹ ijọ naa.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe Agba fun ijọ GOFAMINT , Pasitọ S.O Omowumi fi sita ni ọjọ keji, oṣu Karun-un, lo ti kọkọ kede iku naa.
O ni "pẹlu ẹdun ọkan, ṣugbọn ni itẹriba fun aṣẹ Ọlọrun Olodumare, ni a kede iku arakunrin wa, pasitọ wa, ati ọkan lara ọmọ igbimọ oludari ijọ...
Pasitọ Emmanuel Abina, to ku l'Ọjọru, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2021.
O ni awọn yin Ọlọrun, fun igbeaye oloogbe ati ipa to ni ninu ijọ, paapaa laarin awọn ọdọ.
"Ki Jesu Kristi, Oluwa wa, ko tu Oludari wa, idile, ati ẹbi, to fi mọ ijọ ninu."
- Àwọn Olùkọ́ Yorùbá ní ìpínlẹ̀ Osun ṣe bẹbẹ lórí ètò Akomọlede àti Aṣa lórí BBC
- Gba abẹ́rẹ́ Covid-19 kí o fi ọtí, "Doughnut", ẹ̀bùn owó ọ̀fẹ́ ṣararindin
- Ìyàwó Adeboye gbàdúrà fún Nàìjíríà ní ìgbà akọkọ tó fara hàn lẹ́yìn ikú ọmọ wọn, Dare
- 'A kò bomi sí ara tàbí lọ balùwẹ̀ fún odidi ọjọ́ 56 tí a fi wà ní páńpẹ́ àwọn ajínígbé'
- Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Akeredolu tó gbá ìyàwó mi létí ó bá má lọ lọ́fẹ̀ẹ́ - Ọkọ Aláboyún
- Egúngún bá òṣèrébìnrin lòpọ̀ nínú eré, àwọn Eléégún yarí
















