Shebaby: Àwọn Eléégún ní òṣèré yóò kú láàrin ọjọ́ méje

Oríṣun àwòrán, Seyi Ariyo Shebaby Instagram
Yoruba ni ẹnikan kii gbọ ọjọ iku rẹ ko dakẹ, eeyan ko si le mọ ọjọ to maa ku, ki inu rẹ dun.
Idi ree ti gbajumọ osere tiata lobinrin kan, Seyi Ariyo, ti ọpọ eeyan mọ si Shebaby se bu sẹkun, to si n figbe ta.
Ariyo, ẹni to bu sẹkun ninu fidio kan to gbe soju opo ayelujara Instagram rẹ salaye pe fiimu kan ni oun ya, eyi to fẹ fa iku ojiji ba oun bayii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ní Yàjóyàjó: Pasítọ̀ Dare, ọmọ́ Pásítọ̀ Adeboye ti dágbére fáyé lẹ́ni ọdún 42
- Ikú tó fẹ́ pa Opeyemi Ayeola ṣí i ní fìlà, ló bá ń kọrin ẹ fọ̀rọ̀ mi kọ́gbọ́n
- Nǹkan pàtàkì mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa Salawa Abeni bí ó ṣe pé ọgọ́ta ọdún.
- Ayé ń pè wá ní 'Yeyebrity' torí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha, nǹkan bà wá lágbo tíátà Yoruba"
- Ṣé o mọ àwọn òrìṣà ìṣẹ̀mbáyé méje tó di ilẹ̀ gbogbo àgbáyé mú?
- NECO gbé èsì ìdánwò ọdún 2020 jáde!
- Ganiyu fẹ́ na pápá bora lẹ́yìn tó gún ìya ìyàwó rẹ̀ lọ́bẹ pa lọ́sàán àwẹ, ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́
Ariyo ẹni to n ke si gbogbo ọmọ Naijiria pe ki wọn gba oun, salaye pe fiimu kan to pe akori rẹ ni Asiri Pẹpẹ ni oun ya lọsẹ to kọja.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
"Mo dẹ lo eegun ninu sinima naa, eegun ba osere kan sun ninu ere naa, eeyan kan wa lo foonu rẹ lati ya aworan ọwọ ibi ti egungun ti ba obinrin naa sun.
Ẹni to ya aworan naa wa gbe fidio ibi ti eegun ti n ba onitọun sun sori ayelujara ni awọn eleegun ba ri, wọn ti bẹrẹ si ba mi fa wahala lati ọsẹ to kọja.
Awọn Eleegun ti wa n dunkooko mọ mi pe maa ku laarin ọjọ meje, ẹ jọọ, ẹ gba mi, ẹ ma jẹ ki n ku, mo ti ran gbogbo awọn eeyan si wọn, wọn gbọ ni o."
Shebaby wa n rawọ ẹbẹ pe ki awọn Eleegun dari jin oun nitori oun ko tapa si isẹse, amọ ki wọn fori jin oun, oun ko ni se bẹẹ mọ.
"N ko ni foju tẹmbẹlu asa ajogunba wa laelae, mo se sinima Asiri Pepe lati la awọn eeyan lọyẹ lori ohun to n sẹlẹ ninu ẹsin, eyi to kọja ohun to n waye lori pẹpẹ.
Paapaa julọ, mo tun salaye ewu to wa ninu bi awọn eeyan kan se maa n foju tabuku ẹsin isẹse wa nilẹ Afirika.
Shebaby wa fi ọwọ sọya pe bi sinima naa ba jade, awọn eeyan gan yoo ri funra wọn pe oun ko se sinima naa lati ta ẹrẹ si asa ajogunba wa.



















