Yoruba Film: Ṣé ẹ máa wá ní Pasuma ni mo bí àwọn ọmọ mi tó ń jẹ́ Kuti fún - Jaiye

Oríṣun àwòrán, jayeola_monje
Lori ọrọ ti awọn eniyan ma n sọ pe awọn ọga ọkunrin ninu iṣẹ tiata ma n bere ibalopọ ki wọn to fun wọn ni isẹ, Jaye Kuti ni ko si otitọ kankan nibẹ.
Amọ o fi kun un wi pe, ẹni to ba n wa ifa, ti oun yọju si oun ti ko kan an ni wọn ma n fi ilọkulọ lọ.
Gbajúgbajà òsèré Nollywood, Jaye Kuti wa parọwa si awọn eniyan papa awọn to fẹran iṣẹ tiata lati ni suuru ni idi iṣẹ wọn, ti wọn si mu iṣẹ wọn ni ọkunkundun.
- https://www.bbc.com/yoruba/articles/cg6rk1y37g7o
- https://www.bbc.com/yoruba/articles/cydj3l84g53o
- https://www.bbc.com/yoruba/articles/cpd0nepg8jpo
Lori ọrọ oun ati Pasuma...
Gbajúgbajà òsèré Nollywood, Jaiye Kuti ti ke si awọn ololufẹ rẹ lati jawọ ninu ahẹs pe Pasuma to jẹ gbajugbaja olorin fuji ni ọkọ oun. Pasuma kìí ṣe ọkọ mi o! Lanre Kuti ni mo fẹ́ - Jaiye Kuti
Kuti ni baale ile oun ni Lanre Kuti fun ogun ọdun bayii ti awọn ti ṣe igbeyawo, ti awọn si ti ni awọn ọmọ ninu igbeyawo naa.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Ninu ọrọ rẹ, O ni oun ati Pasuma jọ ṣe fiimu bi ọkọ ati iyawo, ti awọn si wọ asọ igbeyawo, ko to wa di wi pe awọn eniyan bẹrẹ si ni sọ ahẹsọ pe oun fẹ Pasuma.
"Emi ni mo kọ fiimu, Jaiyeola lorukọ mi ninu ẹ ti Pasuma si ṣe ọkọ taa ya fọtọ. Lawọn eeyan ba n ki mi lowurọ ọjọ keji pe mo ku inawo ana.
Jaiye Kuti ẹwẹ fesi pe ọkọ oun jẹ ẹni to ni suuru gan to si mọ wi pe inu ile rẹ ni oun ṣi wa pẹlu awọn ọmọ rẹ to bi fun Kuti.
Gbajugbaja osere tiata naa ni ko tun si otitọ ninu ahẹsọ pe oun fẹ Yinka Quadri, wi pe irọ lasan ni.

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM













