Lagos-Ibadan Express: Ènì mẹ́rin kú, mẹrin míràn farapa nínú ìjàmbá ọkọ̀

Oríṣun àwòrán, TRACE
O kéré tán ènìyàn mẹ́rin ni wọ́n ti fi ìdí ẹ múlẹ̀ pé o ti jẹ́ Ọlọrun nípè nígbà ti àwọn mẹ́rin míràn fara pa yánayàna.
Laarọ kutu owurọ oni ni ọfọ ṣe to mu ẹmi mẹrin dani ti awọn miran wa nile iwosan.
Eyi waye nínú ìjàmba ọkọ to dánikan ṣẹlẹ̀ ni àgbègbè pipeline, Ogere ni marosẹ Lagos-Ibadan Express ní ìpínlẹ̀ Ogun.
Ogbẹni Babtunde Akinbiyi to jẹ́ agbẹnusọ àwọn alabojutó igbokègbodò ọkọ nipinlẹ Ogun (TRACE), ló fìdí ọ̀rọ̀ na múlẹ̀ lowurọ òni (ọjọbọ).
Akinyibi, tọ́ka si pé ìjàmba ọkọ náà ṣẹlẹ̀ ní ààgo mẹrin ààbọ ìdáji pẹlu ọkọ ajagbe dísù pẹlu nọmba ọkọ TKP 653 XA àwọn èèyàn to si ko iṣu.
O ní ìjàmba ọkọ náà kan ènìyàn mẹ́rinla, ọkùnrin mẹtala, òbinrin kan ti ọkunrin mẹrin si kú, ọkunrin mẹrin farapa.
Ati pe lati ọna oke ọya ni oun gbọ́ pé wọn ti n ko iṣu naa bọ wa si Eko.
Ero to ku pọ nítori pe àwọn to ni iṣú ti ọkọ naa ko tun jòkọ sori ẹru wọ́n loke mọtò naa.
"Ìjánú ọkọ náà kùnà lójijì nítori eré àsá pajude to n sa àti pé ilẹ̀ kò i tíí mọ dáadáa, o subu si ẹ̀gbẹ́ kan "
Akinyibi ni okú àwọn ènìyàn náà ti wa ni ilé ikoku si FOS ni Ipara Remo nipinlẹ Ogun nigba ti àwọn to fara pa wà ni ilé iwosan Idera ni Sagamu.
Akinyibi rọ àwọn awakọ̀ láti maa ṣe àmojuto ọkọ wọ́n, ki wọ́n si yee sáré àsápajudé, ki wọ́n si yée rin ìrìn oru.
















