UNICEF: Nàìjíríà ti bí ìkókó 26, 039 lónìí ọjọ́ kíní, oṣù kínií, ọdún 2020

ikoko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, UNICEF ni awọn ọmọ tuntun ti a maa bi ni Naijiria a tó ìdá meje ninu ọgọrun un gbogbo ikoko ti a maa bi lagbaye

Ajọ ìṣọ̀kan àgbáyé lórí ọrọ awọn ọmọde, UNICEF ti kede pe Naijiria a bi ikoko mọkandinlogoji le ni ẹgbẹrun mẹrindinlọgbọn lonii.

Ogbeni Peter Hawkins to jẹ aṣoju ajọ UNICEF ni Naijiria sọ ninu atẹjade ti wọn fi sita pe awọn ikoko ti Naijiria a bi a jẹ ida meje ninu ọgọrun un gbogbo ọmọ ti wọn a bi lagbaye.

O kede pe gbogbo ọmọ ti wọn maa bi lagbaye jẹ mejidinlọgọrin o le ni irinwo ẹgbẹrun o din mejọ.

Hawkins ni orilẹ-ede India ni ọmọ wọn a pọju ti wọn bi ẹgbẹrun mẹtadinlaadọrin ikoko, o le ni irinwo din ni mẹẹdogun nigba ti China a bi ẹgbẹrun mẹrindinlaadọta o le ni ọọdunrun din ikan.

Àkọlé fídíò, 2020: Oloye Awurela Ifaleke ti wúré ọdún ìgbéga fún kóówá

Hawkins parọwa pé ki asiko ọdun tuntun to tun jẹ ibẹrẹ ọdun mẹwaa miran yii jẹ asiko ironu ati asiko ti eeyan n ṣe isiro ni gbogbo ọna.

O ni o yẹ ki a ronu lori idagbasoke awọn ewe Naijiria ati ipese ọjọ iwaju rere fun awọn ọmọ wa.

Hawkins ni miliọnu meji abọ awọn ọmọde lo ṣalaisi laarin oṣu kan ti a bi wọn lagbaye.

O fidiẹ mulẹ pe ẹgbẹrun okooo le ni ọọdunrun o din meji ati eedẹgbẹta le ni mejilelogun ninu awọn ọmọde to ṣalisi yii jẹ ikoko Naijiria ti wọn ku lati ọwọ awọn aisan ti a le dena.

iya ati omo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, UNICEF ni awọn ọmọ tuntun ti a maa bi ni Naijiria a tó ìdá meje ninu ọgọrun un gbogbo ikoko ti a maa bi lagbaye

Aṣoju UNICEF ni o le ni ẹgbẹrun lọna irinwo awọn ikoko ọmọ Naijiria lo ni awọn alaboyun n bi ku lọdọọdun ni Naijiria.

Lẹyin orilẹ-ede India, China ati Naijiria to ṣe ipo kẹta, awọn orilẹede ti wọn tun ti bi ọmọ to pọ no Pakistan (!6, 787); Indonesia (13, 020); America (10, 452); Democratic Republic of Congo DRC (10, 247); ati Ethiopia (8, 493).

Àkọlé fídíò, 'Òṣìṣẹ́ Bánkì ni mí l'Amẹ́ríkà kí n tó bẹ̀rẹ̀ Tíátà'

O gba awọn eniyan Naijiria niyanju lati pese iranlọwọ nipa ipese ohun eelo, awọn oṣiṣẹ eleto ilera lati maa ra awọn ikoko pada lọwọ iku ojiji.

Ile iṣẹ iroyin Naijiria ni Hawkins ni iku awọn ikoko yii le din ku ni 2020 ti onikaluku ba risi eto ilera alaboyun lẹgbẹ rẹ.

Àkọlé fídíò, 'Mí ò ya wèrè, mí ò burú, ọ̀nà àtijẹ là ń wá'

Hawkins ni o ṣeeṣe ki a dena iku awọn ọdọ wẹẹrẹ wọnyii paapaa ninu ọdun mẹwaa miran ti a bẹrẹ yii ti gbogob ijọba ba gbe igbesẹ to yẹ.

Aṣoju UNICEF ni tolowo ti mẹkunnu ni Naijiria lo ni iṣẹ latiṣe ki nkan le yipada lori iku awọn ewe Naijiria.

O ni ṣiṣe eto ikọni fawọn oṣiṣẹ eleto ilera ati ririsi eto ipolongo Every Child Alive naa a tun din iku awọn ikoko yii ku.

Àkọlé fídíò, #Queen Dihya: Obinrin tó gbógun tàwọn agbésùnmọ̀mí ni Algeria