UNICEF n fìdí òòtọ́ múlẹ̀ pé wọn kò ṣalamí fún Boko Haram ni Nàìjíríà

obinrin kan ati ọmọ

Oríṣun àwòrán, @unicef_Nigeria

Àkọlé àwòrán, UNICEF jẹ ajọ agbaye to n risi ọrọ awọn ọmọ wẹwẹ

Lọjọ Ẹti ni ilé iṣẹ ologun Naijiria fofin de iṣẹ́ àwọn oṣiṣẹ ajọ UNICEF to wa ni ẹkun ila oorun ariwa Naijiria.

Wọn ṣe ofin yii lataari ẹsun ti awọn ọmọ ogun iṣẹ akanṣe Operation Lafiya Doole to n gbogun ti àwọn agbesunmọmi ni ila oorun ariwa Naijiria fi kan wọn.

Ile iṣẹ ologun fi atẹjade sita pe awọn ti gbẹsẹ kuro lori òfin náà lẹyin ọpọlọpọ ijiroro ati ẹbẹ.

unicef

Oríṣun àwòrán, @unicef

Àkọlé àwòrán, Gbogbo nkan nipa ọmọ ọwọ lo jẹ ajọ UNICEF logun lagbaye

Ẹ̀sun ti wọn fi kan ajọ UNICEF ni pe wọn n ṣalami fawọn alakatakiti ẹsin Islamu, Boko Haram ni ẹkun Naijiria naa.

Oṣu mẹta ni ile iṣẹ ologun fi sọ pe UNICEF ko gbọdọ ṣiṣẹ ni ẹkun naa ni eyi ti ajọ UNICEF n gbiyanju lati fidi ootọ mulẹ si lori ẹsun naa.

unicef

Oríṣun àwòrán, @unicef

Àkọlé àwòrán, Ajọ UNICEF maa n pese iranwọ fawọn ewe kaakiri ibi ti ija tabi ọ̀dá ba ti n ṣẹlẹ

Ọgagun agba Onyema Nwanchukwu to jẹ agbẹnusọ fun Ikọ ọmọ ogun naa gba awọn oṣiṣẹ arannilọwọ ti ọrọ kan nimọran pe ki wọn yẹra fun iwa aitọ ki wọn ma baa ṣakoba fun iṣẹ akọni tawọn ọmọ ogun n ṣe lati gbogun ti awọn Boko Haram.

Bẹẹ eyi kọ ni igba akọkọ ti wọn yoo firu ẹ̀sùn bayii kan ajọ UNICEF ni ẹkun ọhun.

Àkọlé fídíò, Omi titun ti rú nínú oríṣii ètò ìgbéyàwó Yorùbá lásìkò yí

Lẹyin ijiroro wọn ti ile iṣẹ ogun gbẹse kuro lori ofin naa ni ajọ UNICEF ti ṣalaye fun BBC pe awọn naa yoo fi bi ọrọ ṣe ri lọdọ tawọn sita laipẹ.

Loṣu kẹrin ọdun yii ni ile iṣẹ ologun lawọn ko fẹ ba oṣiṣẹ ajọ UNICEF mẹta ṣe papọ mọ lataari ahesọ ẹsun pe awọn ọmọ ogun ilẹ n fipa ba awọn kan lopọ ni eyi ti awọn ile iṣẹ ologun pada yipada.